Gbèsè tí iye rẹ̀ tó ₦76b ni Oyetola fi sílẹ̀ fùn wa – Ìjọ̀ba Osun

Adeleke and Oyetola

Oríṣun àwòrán, @Ibrahimmaurufg1

Ijọba ipinlẹ Osun ti fẹsun kan ijọba Gboyega Oyetola to ṣẹṣẹ kuro lori alefa pe gbese ti iye rẹ to biliọnu mẹrindinlọgọrin naira lo fi silẹ de oun.

Agbẹnusọ gomina ipinlẹ naa, Olawale Rasheed, sọ pe akọwe agba ileeṣẹ eto iṣuna, Bimpe Ogunlumade lo fi ọrọ naa lede lasiko to n sọrọ lori ibi ti eto iṣuna ipinlẹ naa de duro.

O ni awọn gbese naa jẹ awọn owo oṣu, owo ifẹyinti atawọn owo mii to yẹ ki ijọba ana ti san lasiko to wa lori oye.

O ni “Ijọba Osun ti ṣawari gbese gọbọi kan to jẹ owo oṣu, owo ifẹyintin, atawọn owo mii to yẹ ki ijọba ana ti san ṣaaju, eyii ti iye rẹ to biliọnu mẹrindinlọgọrin naira.”

“Awari yii lodi si ọrọ ti gomina ana sọ ṣaaju pe biliọnu mẹrinla naira ni oun fi silẹ silẹ de ijọba tuntun, atawọn ọrọ mii to sọ, eyii to jẹ irọ nla gbaa.”

Gẹgẹ bii ọrọ ti akọwe agba ipinlẹ naa sọ, bi isọri awọn gbese naa ṣe lọ ree:

  • Gbese owo oṣu: ₦29,875,191,128.64
  • Gbese owo ifẹyinti: ₦45,375,237,693.40
  • Gbese owo Group Life Assurance Scheme: ₦554,644,028.97

Apapọ iye gbese naa: ₦75,805,072,851.01

O pari ọrọ rẹ pe “A fẹ ki gbogbo araalu mọ pe kii ṣe iye gbogbo gbese ti ijọba ana jẹ silẹ fun wa ree o, a oo maa bu yin gbọ nipa awọn gbese to ku to ba di lọla.”

Ẹwẹ, lasiko ti gomina ana, Gboyega Oyetola n gbe ọpa aṣẹ ipinlẹ naa silẹ, lara awọn nnkan to sọ ni pe oun ko jẹ awọn oṣiṣẹ kankan lowo, bẹẹ naa ni oun fi owo ti iye rẹ to biliọnu mẹrinla naira kalẹ fun ijọba tuntun to n bọ.