Fídíò, Wọ́n fún mi ní “sack letter” lẹ́yìn tí ìyá mi kúnlẹ̀ bẹ̀ wọ́n láti sọ ìdí tí mi ò fi lè lọ ọ́fíìsì – Raymond Adegoke, Duration 8,50

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Raymond Adegoke Cerebral Palsy: Ìgbà tó tó àsìkò tó yẹ kó jókòó, kó máa fà, ohun tójú wa rí nìyí – Ìyá

Ohun ti oju Ọgbẹni Raymond Adegoke ri gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba to tun wa jẹ akanda eeyan kii ṣe kekere.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Raymond sọ bi iṣẹlẹ to ṣẹlẹ sii ṣe ba a ninu jẹ to tun wa di nkan to di ija ofin laarin rẹ ati ile iṣẹ ijọba to n ba ṣiṣẹ.

“Mo kunlẹ, mo bẹbẹ, mo ṣe gbogbo ẹ, amọ o ni ka ṣi maa lọ na afi ti gomina ba to ni ki oun gba a”.

Iya rẹ ni wọn ba fun oun ni lẹta kan pe ki oun fun ọmọ rẹ, igba ti wọn ṣi i wo lo ba di iwe idaduro lẹnu iṣẹ.

Ẹni Ogoji ọdun ni Raymond to ni aisan to ni ṣe pẹlu iṣan eyi ti oloyinbo n pe ni Cerebral Palsy.

Raymond ni nkan to n ṣe oun fara jọ ohun ti olyinbo n pe ni “Cerebral Palsy” amọ orukọ ti eyi n jẹ gangan oun ko le sọ ọ.

Iya rẹ to ṣalaye ohun to la kọja gẹgẹ bi abiyamọ ṣalaye fun BBC pe ẹni to ba ri Raymond ni kekere ko le mọ pe bi ọrọ rẹ ṣe maa ri leleyii.

“Mo maa gbe e joko, emi a joko sẹyin rẹ, mo maa ju nkan si i niwaju lati mọ boya yoo gbera. Igba to to ko lọ ile ẹkọ, mo maa n gbe e pọn ni”.

O ni “igba ti mo bi i, o pupa, o rẹwa, ko sẹni to le mọ pe bi yoo ṣe pada ri leleyii”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Iya rẹ, Aderibigbe Margaret Adebisi sọ pe Raymond yege ninu gbogbo idanwo rẹ titi to fi ka ile ẹkọ girama to tun yege wọ ile ẹkọ giga fasiti to kẹkọọ gboye.

Raymond kọ lati jẹ ki aipe ara rẹ da a duro lati laluyọ laye. O wa ṣalaye bo ṣe bori gbogbo ipenija yii toun naa si di ẹni to riṣẹ to n lọ ọfiisi amọ ṣe ni orin tun yipada ti oniruuru iṣẹlẹ waye ti wọn fi da a duro ni ile iṣẹ rẹ koda ti gomina ipinlẹ naa d a si i.

Bo tilẹ jẹ pe Raymond ni wọn parọ mọ oun ni pe o to ọdun kan ti oun ti wa ibi iṣẹ gbẹyin, awọn aṣoju ijọba sọ fun BBC Yoruba pe bi wọn ba fẹ ẹri, awọn lee gbe faili rẹ jade.