Ilé alájà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Salvation Ministry ń lò dàwó, Ọlọ́pàá ní èèyàn mẹ́ta ní wọ́n rí tó ti kú

Ile alaja to dawo

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe ile kan ti ijọ Salvation Ministry n lo fi ṣe isin ti dawo ni olu ilu ipinlẹ Delta, Asaba.

Ohun ti Ọlọpaa ipinlẹ Delta ti fi sita ni pe ni titi di alẹ ana ti iṣlẹ naa ṣẹlẹ, wọn ti ri eeyan mejidinlogun yọ kuro labẹ ile naa ti eeyan mẹta si farapa gidi gan.

nigba to fi di owurọ yii, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Delta, DSP Bright Edafe sọ fun BBC pe eeyan mẹta lo ti ku nibi iṣẹlẹ naa ti wọn lee fi aridaju rẹ han.

DSP Bright sọ pe kii ṣe ootọ pe eeyan mẹwaa lo ku gẹgẹ bi awọn oniroyin kan ṣe n sọ ọ o si fi kun un pe akitiyan ṣi n lọ lati doola awọn eeyan nibi iṣẹlẹ ọhun tori awọn oṣiṣẹ pajawiri ṣi wa nibẹ ti wọn n ṣiṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ṣalaye wipe ijọ naa n ṣe isin lọwọ loke ile naa ni nigba ti ile naa dede dawo amọ o ni ile naa ko dawo taara lori gbogbo awọn eeyan naa tori naa awọn kan ribi jade ninu ile naa.

Ọwọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ti ijọ naa n ṣe eto awẹ ati adura ọlọjọ mọkanlelogun.

Ile iṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Delta, ile iṣẹ panapana ati ọlọpaa lo wa nibi iṣẹlẹ naa ti wọn si n wadii lati mọ boya awọn eeyan ṣi ha si abẹ ile naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ