Wo ọkùnrin àkọ́kọ́ tí yóò lo ọkàn ẹlẹ́dẹ̀ láti mi

Ọkunrin ọmọ orileede Amerika kan, David Bennett, ti di ẹni akọkọ l’agbaye ti awọn dokita yoo paarọ ọkan rẹ si ti ẹlẹdẹ lati ipasẹ isẹ abẹ to lagbara.David Bennett, eni odun mẹtadinlọgọta ni ara rẹ ti n m’okun lẹyin ọjọ mẹta ti iṣẹ abẹ oniwakati meje naa waye nilu Baltimore.Awọn dokita nile iwọsan fasiti Maryland gba asẹ lati ọwọ igbimọ to n s’akoso eto ilẹra ki wọn to ṣe iṣẹ abẹ naa.

Idi ni wipe ọgbeni Bennett ni aisan okan aṣekupani to le yọri si iku, ti iṣẹ abẹ naa ko ba waye.Awọn akọṣẹmoṣẹ ti sọ saaju pe alaisan naa ko le gba ọkan eeyan, eleyi to jẹ igbesẹ ti awọn dokita maa n gbe nigbati aisan ọkan alaarẹ kan ba l’agbaraẸlẹdẹ, ti wọn se atunse iseda re pẹlu iwadii imọ isegun igbalode, ni awọn dokita ti yo gbogbo ohun to le tako ẹjẹ Bennett kuro lara rẹ, ki wọn to se ise abẹ naa.

Gẹgẹ bi olori ikọ awọn dokita to ṣe iṣẹ abe naa,Bartley Griffith se wi, aṣeyọri iwadi imọ isegun fun ọpọlọpọ ọdun ni isẹ abẹ naa jẹ, eleyi ti yoo mu ayipada de ba igbesi aye awọn eeyan kaakiri agbaye.Nigba to n ba BBC sọrọ, Griffith sọ pe isẹ abẹ naa yoo tubọ sun iran ọmọniyan mọ wiwa ọna abayọ si isoro aito eya ara fun iwosan awọn alaarẹ.