Fídíò, Ọkùnrin tó fẹ́ fipábámilòpọ̀ fín ǹkan sí mi lójú nínú ọkọ̀, mó sá wọ igbó àmọ́…, Duration 3,46

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gender Based Violence: Àjàkálẹ̀ àrùn míì ní ìfìpábánilòpọ̀ níbí pẹ̀lú adúrú obìnrin tí wọ́n ṣeé sí

Pẹlu omije loju, Zahara sọ bi ọkunrin naa to ba a rinrin ajo pọ ṣe ri i mu nipa dida nkan si i loju ti ko fi lee mọ ohun to n ṣe mọ́.

Zahara yan lati ma fi itiju ba tara rẹ jẹ. Lẹyin ti wọn gbiyanju lati fipa ba a lopọ, ko joko tẹtẹrẹ lati maa sọkun tabi wa oju aanu kiri.

Bi ata ni, bí afẹ́fẹ́ tajutaju ni, Zahara ko ṣaa le mi tabi riran.

Zahara

O gbiyanju lati gba ara rẹ la ṣugbọn ko sọna. Oreọfẹ kan ṣoṣo to ni ni asiko ti ọkunrin naa kan jade lọ mu nkan lẹyin ọkọ. Lai riran, lo ba tu u sigbo.

Ohun to ṣẹlẹ lẹyin naa ni Zahara ṣalaye fun BBC.

Zahara

“Wọn maa n ro pe awọn lẹtọ si obinrin, bii pe ohun to yẹ ko jẹ tiwọn ni”.

O ti le ni ẹẹdẹgbẹrin-le ẹgbẹrun meji obinrin ti wọn ti fipa balopọ lorilẹede South Africa lọdun to kọja nikan.

Nibayii, Zahara ti di gbajugbaja olorin to n kọrin pọ mọ tita jita funrarẹ.

Ko sẹni to kọ |ahara bi wọn ṣe n ta jita lohun to jẹ pe owo gọbọ́i lawọn eeyan n na lati kọ ọ.