Àwọn ẹ̀ka Krìstẹ́nì nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC Àríwá buwọ́lu Obi/Datti

Aworan

Oríṣun àwòrán, Peter Obi

Ẹka awọn ẹlẹsin Kristẹni ninu ẹgbẹ oṣelu All progress Congress ni apa ariwa orilẹede Naijiria, ti ni ki awọn alatilẹyin ṣe atilẹ fun oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ninu eto idibo aarẹ to n bọ lọdun 2023.

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa, Babachir Lawal, ẹni to jẹ akọwe ijọba apapọ tẹlẹ ni awọn ti pinu lati ṣe atilẹyin fun Peter Obi ati igbakeji rẹ, Yusuf Datti Baba Ahmed lẹyin ọpọlọpọ ijiroro, ti awọn si fẹ ko jawe olubori.

Ẹgbẹ naa ni ipinu ẹgbẹ oṣelu APC lati mu aarẹ ati igbakeji lo fi ara jọ iwa eṣu, ti wọn si n wa ọgbọn lati fi tipatipa mu awọn ọmọ orilẹede Naijiria sinu ẹsin ti wọn, paapa ju lọ awọn to wa ni igun ti ariwa lorilẹede yii.

Lawal wa sapejuwe Bola Tinubu gẹgẹ bii ẹni ti ko ni anfani kankan to fẹ ṣe fun ilọsiwaju orilẹede yii pẹlu igbakeji rẹ, Kashim Shettima.

O tẹsiwaju pe awọn ni igbagbọ ninu oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Obi/Datti lati pese ọna abayọ fun orilẹede Naijiria lọwọ laasigbo eleyi ti wọn ti da silẹ.

“Obi/Datti ni a ni igbagbọ pe yoo pese ọna abayọ lorilẹede Naijiria lẹyin ti awọn abaye jẹ kan ti ṣe basubasu.

“Awọn ọmọ orilẹede Naijria gbọdọ fura si awọn ẹgbẹ oṣelu kan to ni erongba buburu fun ilọsiwaju, ti wọn si fẹ da ija ẹsin ati ẹlẹyamẹya silẹ fun awọn eeyan wa.

“Ẹgbẹ oṣelu Labour Party nikan ni a tẹle nitori a mọ pe wọn maa mu irọrun de ba awọn eeyan wa. A wa kesi awọn eeyan lati tẹle Obi/Datti nitori awọn nikan ni ọna abayọ.”