Wọ́n fi àdúgbò kan sọrí ààrẹ Buhari ní Niger Republic, ẹ fójú lóúnjẹ

Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Ọjọbọ ọsẹ yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari balẹ siluu Niamey, lorilẹ-ede Niger Republic fun ipade ọlọjọ meji kan nipa ọrọ aje laarin awọn orilẹ-ede ni Afrika.

Buhari tun fi anfaani ipade ọhun ṣi adugbo kan ti wọn fi sọri rẹ, iyẹn Muhammadu Buhari Boulevard, eyii ti ijọba Niger fi da a lọla.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ Buhari, Garba Shehu fi lede loju opo Twitter rẹ, o ni Aarẹ tun lọ sibi ayẹyẹ ifilọlẹ iwe kan nipa rẹ, eyii ti wọn kọ ni ede French.

Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Orukọ iwe naa ni “Muhammadu Buhari: The Challenges of Leadership in Nigeria.”

Lara awọn to ba Buhari lọ si Niger ni minisita eto iṣuna, Zainab Ahmed; olubadamọran nipa eto abo, Major-General Babagana Monguno (rtd); ati ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ, Ahmed Rufai Abubakar.

Nibi eto ọhun ni Aarẹ Niger, Mohamed Bazoum, ti da awọn ọmọ Naijiria mẹrin lọla fun akitiyan wọn lori  igbelarugẹ karakata laarin orilẹ-ede mejeji.

Awọn eeyan ti Bazoum da lọla ni minisita eto irina ọkọ ofurufu, Hadi Sirika; alaga ileeṣẹ Oriental Energy Resources, Mohammed Indimi; adari ileeṣẹ MRS Holdings Limited, Sayyu Dantata; ati eekan inun ẹgbẹ oṣelu APC, Aliyu Farouk.

Lara awọn aworan abẹwo Buhari si Niger ree;

Buhari

Oríṣun àwòrán, @GarShehu

Buhari

Oríṣun àwòrán, @GarShehu

Buhari

Oríṣun àwòrán, @GarShehu

Buhari

Oríṣun àwòrán, @GarShehu