Fídíò, Inú ìrírí tí mo rí ni mo ti máa ń rí ìmísí fún àwọn fọ́nrán mi- Mc Lively, Duration 6,29

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

MC Lively: Nítorí pé mo máa ń bínú púpọ̀ nínú àwọn fọ́nrán mi àwọn èèyàn kò mọ̀ pé mo fẹ́ràn láti máa rẹ́rìn ín

Micheal Sanni Amanesi Aluyon Pius to je gbajugbaja alawada gbalejo BBC Yoruba.

O ni egbẹ̀rún márùn ún naira ni owó osù akọ́kọ́ ti òun gba lẹ́nu isẹ́ agbẹjọ́rò kí òun tó kúrò níbẹ̀ yà sí aláwadà báyìí.

Mc Lively salaye pe oun wà láti ipinle Edo ṣùgbọ́n ilẹ̀ Odùduwà, ni Ile Ife ni ipinle Osun ni guusu iwo oorun Naijiria ni wọn bí oun si ti o si dagba nibe.

Eyi lo je ki ede Yoruba dun lenu re pupo.

Mc Lively ni pe: Torí pé mo maa n bínú nínú àwọn fọ́nrán mi ni àwọn èèyàn kò se mọ pe mo fẹ́ràn láti má a rẹrin.

Alawada MC Lively

Nibo ni Michael Sanni ti n ri awon awada re gege bii orisun?

Amanesi Aluyon Pius ni pe ẹ̀wà ni ounje ti oun feran julo lati maa jẹ de ibi pe oun lè jẹ ẹ̀wà pẹ̀lú spagetti.

Bakan naa lo salaye fun BBC orisun irir re pe: Inu ìrírí ti mo ri ni mo ti má rí imisi fún àwọn fọ́nrán mi.Mc Lively.

Ninu Ifọrọwanilẹnuwo pẹlu Mc Lively aderinposonu Naijiria yii naa lo tun ti sọ nipa awọn ipenija to ti koju ri lasiko to n wa ise.