Kini Wòlíì rí tó fí yìnbọn lú arábìnrin ẹní ọdún 18 tó sá wọ ilé ìjọsìn rẹ́?

Aworan afurasi wolii to yinbọn lu arabinrin kan

Oríṣun àwòrán, Ogun Police Command

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti kede pe awọn ti mu wolii ile ijọsin kan fẹsun pe o gbiyanju lati pa eniyan ati pe o ni nkan ija oloro lọwọ lọna aitọ.

Wolii ile ijọsin Cele kan to wa ni orita Olambe, Akute ni ipinlẹ Ogun la gbọ pe o dabọn bo arabinrin kan lẹsẹ lasiko to sa asala wọ ile ijọsin rẹ.

Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun DSP Abimbola Oyeyemi ti ṣe sọ,awọn mu Pasitọ Ayodele Omope lẹyin ti eeyan kan pe awọn nipe pajawiri.

Ki lo fa ati wolii yinbọn mọ alaiṣẹ?

Ohun taa ri ka ninu atẹjade ọlọpaa ni pe arakunrin to kesi awọn lori ago, Deji Olaketan jẹ alabaṣiṣẹpọ pẹlu arabinrin ti Pasitọ naa yinbọn lu lẹsẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olaketan sọ fun awọn ọlọpaa pe oun ati arabinrin Kemi Johnson n dari pada sile lẹyin tawọn lọ ja ọga wọn si papakọ ofurufu nibi to ti wọ baalu lọ si irinajo.

O ni bawọn ṣe n pada bọ lẹyin ti awọn gbe ọkọ lọ si ile mọlẹbi ọga wọn awọn gbọ pe awọn oloro wa ni agbegbe Olambe.

Nitori pe ilẹ ti ṣu ,Deji sọ pe awọn sa asala wọ ile ijọsin Cele kan ti wọn ti nṣe aisun isọji.Ẹnu ọna lo s pe awọn duro si ti wahala fi bẹ silẹ.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ,afurasi wolii ti ọlọpaa mu yi ṣadede jade to si yinbọn lu arabinrin Kemi Johnson lẹsẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọlọpaa lawọn n tẹsiwaju pẹlu iwadii

Awọn ọlọpaa ẹka Ajuwon lo sare wa sibi iṣẹl naa lẹyin ipe lati ọdọ Deji.

Wọn mu wolii ti wọn si gba ibọn ati ọta ibọn marun un ti ko ti yin lọwọ rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lọwọlọwọ, arabinrin Kemi n gba itọju nile iwosan Igbobi to wa nilu Eko.Ṣaaju wn ti gbe lọ si ile iwosan nla Ijaye ati ile iwosan fasiti ilu Eko.

Ẹwẹ Kọmisana ọlọpaa Lanre Bankole ti ni ki wọn gbe afurasi yi lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ki iwadii si tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yi.