Ìjọba àpapọ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìkọlù Russia sí Ukraine àti ìgbésẹ̀ rẹ̀ lórí àwọn ọmọ Naijiria tó wà níbẹ̀

Russia attacks Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba Naijiria ti ke si orilẹ-ede Rusia lati dẹkun ikọlu ṣiṣẹ si orilẹ-ede Ukraine.

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama, lo fi ọrọ naa lede nibi ipade awọn akọroyin kan to waye niluu Abuja.

Eyii lo waye lẹyin to ti kọkọ ṣe ipade pẹlu awọn aṣoju ilẹ okeere, ti aṣoju ilẹ Gẹẹsi ati Amẹrika wa lara wọn.

Onyeama tun ṣe ipade pẹlu aṣoju ijọba orilẹ-ede Ukraine si Naijiria, Kirdoda Valerii ati aṣoju orilẹ-ede Russia si Naijiria, Alexei Shebarshin.

O ni ijọba Naijiria fi akoko ipade naa pe fun alaafia ati ọna ti awọn orilẹ-ede memeji yoo fi yanju ede aiyede to wa laarin wọn.

O ni “A rọ awọn mejeji ki wọn gba alaafia laaye, amọ o ba wa ninu jẹ pe ifọrọwerọ to n waye laarin awọn mejeji tẹlẹ fori ṣọpọn.”

Nigeria Ministry of Foreign Affairs

Oríṣun àwòrán, Ministry of Foreign Affairs

“A jẹ ko ye wọn pe Naijiria ko fọwọ si ikọlu ti Russia n ṣe si Ukraine a gba si gba nimọran lati ko ọmọ ogun rẹ ni Ukraine.”

“A ni ibaṣepọ pẹlu Ukraine, ọmọ ẹgbẹ iṣọkan agbaye, UN, ni wọn, bẹẹ si ni Russia naa ṣe jẹ.”

“A gbabọ pe orilẹ-ede olominira ni Ukrain, a si fọwọ si pe ki Russsia dẹkun ikọlu ṣiṣẹ si Ukraine, ko si ko awọn ọmọ ogu rẹ pada si Russia.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ijọba apapọ yoo ko awọn ọmọ Naijiria kuro ni Ukraine

Ẹwẹ, ijọba apapọ ti sọ pe oun yoo ko awọn ọmọ Naijiria kuro ni Ukraine ni bayii ti Russia n kọlu orilẹ-ede naa lemọ-lemọ.

Eyii lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti ọọfisi ijọba Naijiria to wa ni Poland fi ṣọwọ si ileeṣẹ iroyin abẹle Channels lọjọ Abamẹta.

Ninu fidio kan ti alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa fi lede loju opo Twitter rẹ, o ni eto ti wa nilẹ lati ko awọn eeyan naa kuro ni Ukraine.

Dabiri-Erewa rọ awọn eeyan naa lati lọ si eti ibode Ukraine si Poland tabi tiRomania tabi awọn eti ibode to ba sun mọ wọn julọ.

O tun fi awọn nọmba ti wọn le pe sita fun iranlọwọ ni kankan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ