Fídíò, A kò tíì mọ ẹgbẹ́ òṣèlú tí a máa bá lọ sùgbọ́n a ti mọ̀ àwọn méjì tí a kò fẹ́- Khadijat Okunnu-Lamidi, Duration 6,28

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Khadijat Okunnu Lamidi: Olùdíje sípò aàrẹ Nàìjíríà tó sọ pé ǹkan gbódọ̀ dàrú ní Nàìjíríà kò tó níyanjú padà

Ta ni Khadija Okunnu Lamidi?

Laarin iṣẹju diẹ ti eeyan ba joko ti Khadijat, yoo ri pe ọlọpọlọ pipe ni.

Khadijat Okunnu ni oludije ipo aarẹ obinrin Naijriia fun idibo ọdun 2023 to kọkọ ferongba rẹ han.

Ọdọ ni, oniṣowo ni, o si tun jẹ ẹni to wa lati idile to ṣe pe oṣelu ati isinru jẹ ohun amuyangan.

Kini awọn ńkan mii ti Khadija Okunnu tun so fun BBC?

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Khadijat sọ ohun to mu ki oun gbegba apoti ibo ni orileede to ṣe pe awọn oloṣelu ọkunrin kii saba mu adehun ṣe bi wọn ba dori ipo tan.

”Gẹgẹ bi obinrin mo ri pe awa ni a ni iṣẹ pupọ lati se ninu iṣelu Naijiria nitori awọn to n ṣe ilu wọn yatọ si awọn to n to ilu”

O ṣalaye pe kudiẹ kudie ti oun ri lo mu ki oun gba a lero lati fun Naijiria ni nkan to nilo lasiko yi.

O ni awọn ijọba to ti ṣelu ṣaaju ko ri nkankan ṣe si awọn ipenija to n koju Naijiria lati igbatalaye ti daye bi ọrọ̀ina, eto ẹkọ to peye ati oju ọna to dara.

Khadijat tẹnu mọ pe ”Eto ẹkọ ni Naijiria o dabi pe o ti bajẹ Ko gbọdọ bajẹ́ ju eyi lọ mọ”

Ki lo de ti o ṣe pe idije si ipo aarẹ lo ti bẹrẹ?

Ibeere yi la fi ṣọwọ si Khadijat to je aburo si olori oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ Eko, Hakeem Muri Okunnu.

Baba kan naa lo bi wọn ṣugbọn iya wọn yatọ.

Baba wọn ni gbajugbaja oloṣelu nii nipinlẹ Eko nigba kan ri, oloogbe Lateef Femi Okunnu.

Khadijat ninu alaye rẹ sọ pe ko si ẹniti ko lẹtọ lati dije du ipo to ba wu u lọkan ni Naijiria.

Nitori naa lo loun ṣe yan ipo aarẹ gẹgẹ bi ibi ti oun yoo ti bẹrẹ.

O tẹsiwaju pe ”nkan gbọdọ daru ni Naijiria ko to niyanju pada.

Ati pe, A ko si gbọdọ maa ṣe nkan bi tatẹyinwa ti a ba fẹ iyipada to yatọ”

Yatọ si iṣẹ ti Khadijat ṣe fun igba diẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko, ko dipo oṣelu kankan mu ṣaaju asiko yi to kede pe oun fẹ ṣe aarẹ Naijiria

Khadijat kọ ni yoo kọkọ tọ oju na ati di aarẹ obinrin akọkọ Naijiria

Ninu itan eleyi taa le ranti, Sarah Jibril oloṣelu obinrin ni Naijiria ti gbero lati du ipo aarẹ Naijiria ṣugbọn to kuna.

Lọdun 1992 lo ti kọkọ bẹrẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party ṣugbọn o ṣe ipo kẹrin ninu idibo abẹle ẹgbẹ naa.

O tun gbiyanju lọdun 1998 labẹ asia Peoples Democratic Party ṣugbọn ko ri tikẹẹti ẹgbẹ gba.

Aarẹ ana Olusegun Obasanjo lo fẹ̀yin rẹ janlẹ.

Ko tan sibẹ, Sarah Jubril tun gbiyanju lọdun 2011 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ṣugbọn ibo kan pere lo ri gba ninu idibo abẹnu ẹgbẹ naa.