Ọmọ Nàìjíríà tó há sí Ukraine kò nílò físà láti wọ Romania àti Poland- Ìjọba Nàìjíríà

Ukraine war

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba apapọ ti gbe igbesẹ lori awọn ọmọ Naijiria to n sa kuro ni Ukraine latari ogun ti Russia gbe ka wọn mọle.

Ninu atẹjade kan ti ọọfisi ijọba Naijiria to wa ni Hungary ati Romania fi lede, wọn ni awọn eeyan naa le wọ awọn orilẹ-ede ọhun bayii.

Atẹjade naa ni asọye ti wa laarin awọn ijọba Naiiiria atawọn orilẹ-ede naa lati gba awọn ọmọ Naijiria wọle lai ni “Visa” fun akoko diẹ.

Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ gbé lórí àwọn ọmọ Naijiria tó ń sá kúrò ní Ukraine

Atẹjade lati ọọfisi ijọba Niaijiria ni Romania sọ pe ijọba Romania ti ṣeto lati gba gbogbo awọn eeyan to n sa fi Ukarine silẹ wọ orilẹ-ede awọn.

Ukraine

Oríṣun àwòrán, Buhari Sallau

Wọn ni awọn ẹṣọ aṣọbode Romania yoo gba awọn eeyan naa wọle niwọn igba ti wọn ba ti le ni iwe irinna lọwọ, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ aṣọbode to wa nibẹ.

Ni ti orilẹ-ede Poland, ijọba Naijiria ni awọn eeyan rẹ le lọ si orilẹ-ede ọhun, bakan naa ni wọn kede awọn ibi ti wọn le gba wọle, to fi mọ awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti wọn le pe si.

Ukraine

Oríṣun àwòrán, Buhari Sallau

Ni ti Hungary, atẹjade naa ni awọn ọmọ Naijiria to ba ni iwe igbelu Ukraine ni anfaani lati wọ orilẹ-ede naa.

Eyii lo ṣeeṣe lẹyin ti ijọba Hungary kede pe awọn eeyan naa wọle, amọ wọn gbọdọ ni iwe igbelu pe wọn n gbe ni Ukraine tẹlẹ lọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Eyii to tumọ si pe, kii ṣe dandan ki wọn ni iwe irinna “Schengen Visa” lọwọ.

Atẹjade naa sọ siwaju si pe ijọba Naijiria ti ṣetan lati ṣeto ibi ti wọn yoo de si ni Hungary, amọ wọn gbọdọ ni iwe irinna Naijiria lọwọ, iwe igbelu Ukraine, to fi mọ iwọmba owo diẹ (Euro) lọwọ, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣo aṣobode ilẹ naa.

Ukraine

Oríṣun àwòrán, Buhari Sallau

Idẹyẹsi lẹnubode Ukraine si EU

Ẹwẹ, awọn ọmọ Naijiria kan to n gbiyanju lati fi orilẹ-ede Ukraine silẹ ti ke gbajare lẹyin idẹyẹsi ti wọn n dojukọ lẹnu ibode ati wọ ilẹ EU.

Pupọ ninu awọn eeyan naa ti wọn jẹ akẹkọọ sọ pe awọn aṣobode Ukraine ko gba awọn laaye lati re kọja si odikeji nitori wọn jẹ alawọ dudu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọkan lara wọn to n kẹkọọ nipa imọ iṣẹgun ni fasiti Kharkiv, Ruqqaya, sọ pe oun fẹsẹ rin fun wakati mọkanla lorumọju ki oun to de Medyka-Shehyni, to jẹ ibode Poland si Ukraine amọ wọn ko jẹ ki oun wọle.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gẹgẹ bii ohun to sọ, wọn ko gba laaye lati wọ orilẹ-ede naa nitori wọn ni awọn ọmọ ilẹ Ukraine ni yoo kọkọ wọle, amọ ko le sọ boya ọmọ orilẹ-ede Poland ni awọn aṣọbode naa tabi ti Ukraine.