Olùkọ́ dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tó na akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án lálubami

Cameroon teacher arrested after viral beating video

Oríṣun àwòrán, @lucienbodo

Awọn ọlọpaa ni Cameroon ti fi ṣikun ofin mu olukọ kan, lẹyin ti fidio bo ṣe na akẹkọọ to jẹ ọmọ ọdun mẹsan an jade lori ayelujara.

Iroyin ni iṣẹlẹ naa waye ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan ni Doula, to jẹ ilu ti ọrọ aje rẹ milẹ titi julọ ni Cameroon.

Ogunlọgọ eeyan lo ti pin fidio naa lori ayelujara, eyii to mu ki ọpọ eeyan bu ẹnu atẹ lu iwa ti olukọ naa wu.

Fidio ọhun ṣafihan akẹkọọ naa ni ihoho, ti awọn okunin meji si di ọwọ ati ẹsẹ rẹ mu.

Lẹyin naa ni olukọ ọhun bẹrẹ si fi rọba na akẹkọọ naa, ko to tun bẹrẹ si n fi pẹtẹpẹtẹ ada na.

Gẹgẹ bii ohun ti oṣojumikoro kan sọ fun awọn akọroyin, ijiya naa ko ṣẹyin bi akẹkọọ ọhun ko ṣe le ṣalaye idi ti ko ṣe yọju sile ẹkọ fun awọn ọjọ diẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

Ẹwẹ, ijọba Cameroon ti fofin de ki olukọ maa fiya jẹ akẹkọọ amọ awọn ile ẹkọ kan ṣi maa n da seria fun awọn akẹkọọ wọn.