Ẹ̀yin ọkùnrin Nàìjíríà alágbèrè, ẹ wo iṣẹ́ tí Mike Bamiloye rán sí yín

Ẹyin ọkunrin Naijiiria, ẹ jawọ nibi piparọ obinrin bi ẹni parọ aṣọ.

Gbajugbaja oṣere ẹlẹsin Kristẹni ajihinrere Mike Bamiloye lo n parọwa bayi sawọn ọkunrin lati sinmi piparọ obinrin bi ẹni parọ ” handkerchief”

Bamiloye ti ọpọ mọ fun ere ori itage ”Agbara nla” ni lati ibẹrẹpẹpẹ lo ti yẹ ki awọn ọkunrin mojuto ibaṣepọ wọn pẹlu awọn obinrin.

O ṣakawe lati inu iwe bibeeli bi Samson ti ṣe ṣaṣiṣe nipasẹ iyawo to yan ati awọn obinrin miran to ni ajọṣepọ pẹlu.

O kesi awọn ọdọ iwoyi pe ki wọn ma ṣe fi obinrin ta tẹtẹ nitori ọrọ yi kii ṣe ọrọ awada rara.

O ni bi wọn ba ri piparọ obinrin gẹgẹ bi nkan igbadun adanu ni ytoo gbẹyin rẹ fun wọn.

”Ẹ bi Solomon,ẹ bi Samson, ẹ bi Judah ati Tamar, ko si ọkunrin to moribọ ninu ere gele pẹlu obinrin”