Àwọn agbẹ́bọn tí pa alága ẹgbẹ́ Miyetti Allah tí wọ́n jígbé ní Kaduna- Miyetti Allah

Miyetti Allah

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ awọn darandaran lorilẹede Naijiria, MACBAN ti kede iku Allhaji Abubakar Abdullahi to jẹ alaga ẹgbẹ ni agbegbe Danbardi ni ipinlẹ Kaduna.

Ẹgbẹ Miyetti Allah kede iku rẹ ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Othman Ngelzarma fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Miyetti Allah ni ẹni ọdun mejidinlọgọta ni alaga naa ki awọn agbebọn to ṣekupa a.

”O ti jẹ eniyan marun un ninu ẹgbẹ Miyetti Allah ti awọn agbebọn, ajinigbe ati awọn darandaran ti pa kaakiri orilẹede Naijiria”

”Ẹgbẹ orita ni titi ni wọn ti ri oku Abdullahi lẹyin ti wọn jigbe ni ile rẹ ni Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Kẹsan, ọdun 2021.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Lẹyin ti wọn san owo ẹmi alaga naa ni awọn ajinigbe naa sọ ara rẹ si ẹgbẹ titi ni agbegbe ilu Lere.”

Ẹgbẹ Miyetti Allah wa kesi awọn ẹṣọ alaabo lati ri pe wọn ṣe iwadii iku yii, ki wọn si fi awọn to ṣiṣẹ ibi yii jofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa ni wọn ni kegbare lori eto aabo to dẹnukọlẹ kaakiri orilẹede Naijiria, ti ko si yọ awọn silẹ.

”Ti eleyii ba tẹsiwaju o ṣeeṣe ki o fa idiwọ fun ẹka iṣowo ẹran tita kaakiri Naijiria”

Ẹgbẹ Miyetti Allah wa rọ ijọba apapọ lati gbe awọn eto kalẹ ti yoo mu ki irọrun ba eto iṣẹ ọsin ẹran ni Naijiria.