Ọjọ́ tò burú jùlọ nínú ìrìnàjò oṣèlú mi ni ọjọ ti FFK darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Ojudu

Fani kayode to o ti lo ọpọ aye ati asiko rẹ lati tako aarẹ Buhari to si ti pe ẹgbẹ naa ni onirruru orukọ buruku, orukọ ti oun pẹlu yoo ma jẹ bayii.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ti n fọnmu lẹyin ti minisita eto irina tẹlẹri, Femi Fani Kayode kede ni ọjọ diẹ sẹyin pe oun n darapọ mọ ẹgbẹ oselu All Progressive Party (APC), ti olukuluku si n bẹnu atẹ lu igbesẹ rẹ yii.

Oniruuru orukọ ni awọn eniyan ti fun pẹlu, eyi ko si ṣẹyin iru awọn nnkan to ti sọ nipa aarẹ Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ.

Lẹyin bi ọjọ mẹta ti Femi Fani-Kayode ti kede Igbese yii, ti o si ya fọto pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari ni Aso Rock, sibẹ awọn ọmọ Naijiria ko tii sinmi lori ọrọ rẹ.

Ninu ọpọ ariwisi awọn eniyan ninu awọn iwe iroyin lonii ni awọn miiran ti ṣalaye pe, Femi Fani kayode ti pada sinu eebi rẹ ati pe, o ti darapọ mọ awọn mẹjẹmẹjẹ to tikalara rẹ ti n pario awọn iwa aitọ ti wọn n wu gẹgẹ bi ẹgbẹ ati adari.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wọn ni o wu Kayode ki awọn eniyan maa pe ni awọn orukọ to ti n pe ẹgbẹ oselu naa tẹlẹ , bii “apaniyan, “ọmọ iparun” “alailojuti, iranṣẹ Boko Haram, alaini ibọwọ fun ẹsin ọmọlakeji ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn tun fi kun un pe Fani Kayode ni alailojuti ti ko si iru rẹ miran ni aye yii. ni kete ti foto rẹ jade si ori ayelujara nibi to ti duro pọ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Fani Kayode to o ti lo ọpọ aye ati asiko rẹ lati tako aarẹ Muhammadu Buhari to si ti pe ẹgbẹ naa ni oniruuru orukọ buruku.

Díẹ̀ lára awọn nnkan ti Fani kayode ti sọ sẹyin ree nipa APC ati ijọba Buhari ;

Oniruuru orukọ ni awọn eniyan ti fun pẹlu, eyi ko si ṣẹyin iru awọn nnkan to ti sọ nipa aarẹ Muhammadu Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Fani Kayode

Awọn eniyan wa fesi pe Fani Kayode yoo maa wa ni aarin gbogbo nkan titi lai ni, nitori ko gbona ko tutu ni igba gbogbo.

Ati wi pe, Femi Fani kayode ti fi han pe gbogbo igba ni oun maa n pada sinu eebi rẹ, ati pe ko jẹ tuntun pe o tun le ji ni ọla lati pada sinu ẹgbẹ oṣẹlu People’s Democratic party (PDP)

Ọjọ to buru julọ nínú ìrìnàjò oṣèlú mi ni ọjọ ti FFK darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Ojudu

Mi o nifẹ si lati jẹ ebi rẹ tabi ọrẹ rẹ– Reno Omokiri

Nínu ọrọ to n lọ yii bakan naa, ni Reno Omokiri to jẹ ọkan ninu awọn to ṣiṣẹ labẹ aarẹ Goodluck Jonathan tẹlẹri ti sọ pe, oun ko nifẹ si jijẹ ẹbi tabi ọrẹ Femi Fani Kayode lai.

Loju opo Facebook ti Omokiri kọ ọrọ naa si lo ti fesi si ibere ti wọ́n bi Fani Kayode lasiko to peju sibi Ifọrọwanilẹnuwo ni ile iṣẹ amohunmaworan Channels TV nibi to ti sọ pe ijọba Buhari n lepa Sunday Igboho ati pe ẹbi ati ọrẹ oun ni Sunday Igboho.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Eyi lo wa fa ti Reno Omokiri fi fun lesi pe, O pe igboho ni ẹbi ré , ”o pe Nnamdi Kanu ni ọrẹ ati ẹbi rẹ ati pe o jẹ ọkan ninu awọn ẹni to ni igboya julọ ni Naijiria, sibẹ o huwa esu yi sii wọn?”

”Eyi ń jẹ ki n maa fura si ọ, bawo ni awọn eniyan meji to sunmọ ọ yii pada kangun sinu pampẹ aarẹ Buhari, ti iwọ si lọ darapọ mọ ẹgbẹ APC”

”Ni bayii, mo kọ lati jẹ ọrẹ rẹ tabi ẹbi rẹ.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Obafemi Ojudu ninu ọrọ tirẹ pẹlu ni ọjọ to buru julọ fun oun ni ọjọ ti Femi Fani Kayode darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Obafemi Ojudu to jẹ olubadamọran pataki fun aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrẹ osẹlu ni inu oun ko dun rara pe Fani kayode darapọ mọ ẹgbẹ.

O kọ eyi soju opo Facebook rẹ pe ”oni ni inu mi bajẹ julọ lati igba ti mọ ti bẹrẹ irinajo oṣelu.”

Lẹyin eyi ni Ojudu fi gbogbo awọn nnkan ti Fani Kayode ti kọ nipa ẹgbẹ APC sita loju opo rẹ, paapaa julọ ibi ti o ti sọ pe lai, oun ko le darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ