Ẹ̀wọ̀n ọdún 241 ní wọ́n jù mí sí, lẹ́yìn tí mo lo ọdún 27, mo fojú rí fóònù, haà! Bí mo ṣe ṣe rèé – Bobby

Aworan

Oríṣun àwòrán, BOBBY BOSTIC

Ọkunrin ara orilẹede Amerika kan ti wọn fi sewọn ọdun igba- le-mọkanlelogoji(241) ti ri itusilẹ lẹyin to ti lo ọdun mẹtadinlọgbọn lọgba ẹwọn.

Bobby Bostic ni, aye ti yatọ si bi oun ṣe fii silẹ lọ ninu oṣu kejila ọdun 1995.

Arakunrin yii ri itusilẹ ninu osu kọkanla ọdun to kọja, o ni iyalẹnu lo jẹ fun oun lati ri awọn eeyan to n da sọrọ pẹlu ẹrọ foonu, “awọn miiran n sọrọ sinu ẹrọ gbohungbohun, awọn miran ju ọwọ si ẹrọ omi ti omi si n tu jade”.

Bostic ni nkan miran to ya oun lẹnu ni bi awọn eeyan ti nifẹ ara wọn yatọ si ọgba ẹwọn, o ni ọyaya awọn olutaja wu oun lori yatọ si bi awọn ẹlẹwọn ṣe ma n roju koko ninu ọgba ẹwọn.

O ni ṣaaju ki oun to ri ẹwọn he, ko si aye ati fẹgbẹ kan ara ẹni lopopona nitori ẹru, ṣugbon nisinsinyi ọpọplọpọ lo n kira wọn loju ọna.

Bostic ni aye ti daade bayii nitori gbogbo igba ti oun ba n rin kọja lawọn ọmọde ma n juwọ si oun, eyi ti o ma n mu inu oun dun nitori wipe bẹẹ loyẹ ki igbe aaye ri.

Ọdun 1995 ni Bostic fi ewọn jura nitori pe oun ati ọrẹ rẹ Donald Hutson jẹbi ole jija nigbati wọn fi tipatipa gba ọkọ ayọkẹlẹ lọwọ obinrin kan ti wọn si tun ji nkan lọwọ awọn to n fun awọn alaini lẹbun ọdun keresimesi.

Adajọ alawọ dudu akọkọ ni ipinlẹ Missouri Evenly Baker lo ṣe idajọ Bostic ati ọrẹ rẹ, lẹyin ti o fẹyinti lẹnu isẹ iwe to ka lori bi ọmọde ati agba se n ronu lo mu ko gbe igbesẹ lati rii wipe Bostic ati awọn ọmọ ti o wa labẹ ọdun mejidinlogun ri anfaani idariji lati ọwọ ijọba.

Bostic lo ri idariji ijọba gba lẹyin ti ipinlẹ Boston ṣe ofin titun to dena ki ọmọde to wa labẹ ọdun mejidinlogun maa ri ẹwọn he bii awọn to ti pe ọdun mejidinlogun eyi ti wọn fi se aanu awọn to ti wa lẹwọn ṣaaju ki ofin titun naa to bẹrẹ.

Lẹyin igba ti Bostic ri itusilẹ logba ẹwọn, awọn molẹbi rẹ to to irinwo lo wa ki i kaabọ ti adajọ Baker to ran an lẹwọn naa si wa si ọgba ẹwọn lati gbe e lọ si ile lẹyin ti o ti ri itusilẹ.

Bo tilẹ jẹ wipe ọrẹ rẹ ti wọn jọ fi wọn sẹwọn fun ẹsun ole jija ku lọdun 2018 latari asilo ogun oloro.

AWORAN

Oríṣun àwòrán, ACLU