Peter Obi wọ́ Tinubu lọ ilé ẹjọ́, ó ní kí INEC gba ìwé ẹ̀rí mo yege lọ́wọ́ rẹ̀ fún òun

Bola Tinubu and Peter Obi

Oríṣun àwòrán, @omoelerinjare

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, ti pe ẹjọ tako esi ibo to gbe Tinubu wọle gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria ti awọn araalu dibo yan.

Ẹjọ ọhun, to ni nọmba CA/PEPC/03/2023, ni Obi pe tako INEC, Tinubu, Kashim Shettima ati ẹgbẹ oṣelu APC.

Yatọ si Obi, ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement ati Action Alliance naa tun pe ẹjọ.

Ki ni ipẹjọ naa da le lori?

Ẹbẹ ipejọ naa ni pe Tinubu kii ṣe ojulwo ẹni ti awọn eeyan dibo yan bii Aarẹ lasiko ibo ọhun.

Awọn olupẹjọ naa tun sọ pe ki ile ẹjọ gba iwe ẹri moyege ti INEC gbe fun Tinubu lọwọ rẹ, ko si gbe le Obi lọwọ gẹgẹ bii Aarẹ ti wọn dibo yan.

Awọn olupẹjọ naa tu ni Tinubu ko koju oṣuwọn lati dije du ipo Aarẹ lasiko ti eto idibo naa waye.

Wọn fi kun pe eto idibo naa ko ṣe itẹwọgba nitori awọn kudiẹ kudiẹ to waye ninu rẹ.

Yatọ si eyii, Obi tun ni oun n fẹ ki INEC wọgile eto idibo naa patapata ki wọn si di ibo miran ninu eyii ti Tinubu, Shettima ati ẹgbẹ oṣelu APC ko ni kopa ninu rẹ.

Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii ni eto idibo Aarẹ naa waye.

Oludije ninu ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi lo gba ipo kẹta ninu eto idibo Aarẹ nigba ti Atiku Abubakar ti ẹgbẹ oṣelu PDP wa ni ipo keji.

Igbejọ lori Awuyewuye to suyo ninu eto idibo ma n gba oṣu diẹ lati yanju lorilẹ-ede Naijiria, bo ti jẹ pe ofin ti sọ pe awọn awuyewuye yẹ ki o pari ṣaaju iburawọle fun oludije to yege.

Oseeṣe ki igbejọ lori abajade esi idibo ọdun yii gba akoko pupo ṣaaju.