Èèyàn 5000 ló ti kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ ríri tó wáyé ní Syria àti Turkey

Ile to da wo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iye awọn eeyan to ti ba iṣẹlẹ ilẹ rírí lọ lorilẹede Turkey ni wọn ti to ẹgbẹrun marun, tí awọn miran to si farapa lọ bí ẹgbẹrun meji.

Igbakeji Aare Orilẹede naa Fuat Otkay lo gbe Ikede naa jáde.

Ninu alaye rẹ, O ni o to ẹgbẹrun meje eeyan ti awọn wọ jade lati inu ilẹ, tí ile ti ṣubu le wọn lori.

“O to ẹgbẹrun mẹrin le die ile to da wo ni Orilẹede Turkey.

“Oku to sun ni Syria n lọ bí ẹgbẹrun kan le diẹ.”

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ẹgbẹrun meje eeyan ni wọn wọ jade lati inu ilẹ, ẹgbẹrun meji fara pa

Ní bayi, apapọ àwọn eeyan to tí ba iṣẹlẹ naa lọ ní o ti lọ bí ẹgbẹrun mẹta ati abọ.

Ajọ eleto ìlera lagbaye WHO ti ṣe ikilọ pe o sese kí afikun de ba iye awọn to ba iṣẹlẹ to ile riri naa lọ.

‘ Wọn pariwo síta sugbọn a ko le dọla wọn ‘

Ile tutu, ojo ati ọye to mu lasiko yii wa lara idi ti awọn eeyan ko fi le dọla awọn eeyan to ha si abẹ naa, ti ọpọ wọn si n kígbe síta ni orun mọju fun iranlọwọ.

Ọkùnrin kan ní Hatay pẹlu omije loju lo fi ba ileeṣẹ iroyin Reuters sọrọ lori bí awọn eeyan ṣe n pariwo fún iranlọwọ.

“Wọn n pariwo sugbọn ko si ẹni tí yoo ran wọn lọwọ.

“Inu ìbanujẹ lawa, Ọlọrun… Awọn eeyan yii pariwo pe ki a ran wọn lọwọ sugbọn ko si ẹni kankan níbi latarọ.”

Èèyàn 2300 kú, bí ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírí ṣe wáyé fún ìgbà kejì lónìí ní Turkey

Ilẹ riri

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn to ti padanu ẹmi wọn ninu ilẹ riri to waye ni orilẹ ede Turkey ati Syria ti le ni 2,300 eniyan bayii.

Ileeṣẹ iroyin Turkey ni àwọn to ti ba iṣẹlẹ naa lọ ni orilẹ ede ti wọn nikan ti le ni 1,500, ti awọn to si ti padanu ẹmi wọn ni Syria ti le ni 800.

Ó ṣeeṣe ko jẹ wi pe awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ju bayii nitori iṣẹ ṣi n tẹ siwaju lati yọ awọn to ha sabẹ ilẹ awọn ile to dawo.

Aarẹ Turkey, Erdogan ni awọn ko i tii ri iru akọsilẹ ilẹ riri to le to bẹẹ ri.

O kere tan ẹẹdẹgbẹsan eniyan ni a gbagbọ pe o ti ku lẹyin isẹlẹ ile riri meji to waye ni orilẹ-ede Turkey ati Syria.

Akọsilẹ ijọba nipa awọn to padanu ẹmi wọn nibi ijamba ile riri owurọ yi ni Turkey ti posi, akọsilẹ ijọba ni ẹfadinni -okooleniegbẹrun(1014,) ni awọn to padanu ẹmi wọn gẹgẹ bi olori ajọ ti o gbogunti Ajalu ati iṣẹlẹ pajawiri ti orilẹ-ede Turkey ṣe sọọ.

Iye awọn to padanu ẹmi wọn ni Syria bayi duro ni eejidinlogun-din-ni- ẹgbẹrin (783) ni ibamu pẹlu ile-iṣẹ akọroyin AFP, eyiti o ti n ṣe akojọpọ awọn nọmba awọn to padanu ẹmi wọn ni awọn agbegbe to wa labẹ iṣakoso ijọba ati eyiti owa labẹ iṣakoso awọn alakatakiti.

Apapọ awọn to padanu ẹmi wọn ti le ni ẹẹdẹgbẹsan

O kere tan eniyan aadọrin (70) ni o ti padanu ẹmi wọn ni agbegbe Kahramanmaras ṣaaju ki iṣẹlẹ ile riri keji to ṣẹlẹ,o ṣẹṣẹ ki iye awọn to ti ku lọwọlọwọ posi bi akitiyan lati doola ẹmi awọn to wa labẹ ile riri se n tẹsiwaju.

Ilẹ riri gbẹmi ọpọ eniyan ni afẹmọju ni Turkey ati Syria

Isͅeͅleͅ ileͅ riri ti sͅekoͅlu si agbegbe Guusu- iwoͅ oorun orileͅede Turkey to si ti mu eͅmi oͅgoͅoͅroͅ eniyan loͅ.

Ileesͅeͅ to n risi oͅroͅ oju oͅjoͅ lorileͅede Ameͅrika ni iye iwoͅn ileͅ riri naa to 7.8 magnitude, ti o si rinleͅ to iwoͅn kilomita meͅtadinlogun o le, ni agbegbe Gaziantep.

Ni orileͅede Turkey, awoͅn eͅsͅoͅ alaabo ni o kere tan eniyan meͅtadinlogun lo ti gbeͅmi mi ninu isͅeͅleͅ naa, ti oͅpoͅloͅpoͅ si faraya yanna-yanna.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibeͅru wa pe o sͅeesͅe ki iye eniyan to ba isͅeͅleͅ naa loͅ peleke si ni aipeͅ.

Oͅpoͅloͅpoͅ ile nla lo wo paleͅ , ti awoͅn eͅsoͅ alaabo si ti wa nibeͅ lati doola eͅmi awoͅn eniyan.

Minisita fun oͅroͅ abeͅnu lorileͅede Turkey, Suleymon Soylu ni awoͅn ilu nla meͅwaa ni isͅeͅleͅ naa ti rinleͅ gidididi. Awoͅn si ni ilu Gaziantep, Kahramanmaras, Hatay, Osmaniye, Adiyaman, Malatya, Sanliurfa, Adana, Diyarbakir ati agbegbe Kilis.

Awoͅn ti isͅeͅleͅ naa sͅe oju woͅn soͅ ohun ti oju ri…

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akoͅroyin fun ileesͅeͅ BBC ni orileͅede Turkey ni agbegbe Diyarbakir ni soͅoͅbu itaja nla ni orileͅede naa ti woluleͅ, ti awͅon orileͅede to sunmoͅ Turkey bii Syria, Lebanon ati Cyrus si gburo ileͅ riri naa.

‘’Mo n koͅ nkan loͅwoͅ, sadede ni mo ri ti ileͅ beͅrͅe si ni mi, ti mi o si moͅ ohun to yeͅ ki n sͅe’’

Mo wa leͅgbeͅ ferese amoͅ aya mi n ja pupoͅ pe ki woͅn ma baa wolumi, ohun to sͅeͅleͅ kami laya pupoͅ, ko see fi eͅnu soͅ’’

Akoͅroyin BBC miran to wa ni agbegbe Gaza ni isͅeͅju aaya marundinlaadoͅta ni awoͅn fi ni imoͅlara ileͅ riri naa.

Ni oͅdun 1999, o kere tan eͅgbeͅrun eniyan meͅtadinlogun lo papoda lasiko ileͅ riri to waye nibeͅ.

Orileͅede Turkey w ani gbungun agbegbe ti isͅeͅleͅ ileͅ riri ti ma n waye juloͅ ni agbaye.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images