NÍ YÀJÓYÀJÓ Aṣọ ìbora àti ọ̀pọ̀ èròjà ohun èèlò amáyédẹrùn balẹ̀ sí Turkey fáwọn èèyàn tí ìjàmbá ilẹ̀ ríri kàn

Copyright: temsbaby/Instagram

Gbajumọ akọrin kan lorilẹede
Naijiria, Temilade Openiyi, ti ọpọ eeyan mọ si Tems, ti gba ami ẹyẹ Grammy, akọkọ
iru rẹ ti yoo gba.

Nibi ayẹyẹ igbamiẹyẹ naa
to waye ni agbegbe Crypto.com Arena to wa ni Los Angeles, lorilẹede Amẹrika lo
ti gba ami ẹyẹ naa lọjọ Aiku

Orin to fi gba ami ẹyẹ naa,
“Wait for U”, lo se papọ pẹlu Future and Drake, ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ akọrin ilẹ
Amẹrika kan.

Bakan naa ni wọn tun kede
Tems fun

Bakan naa lawọn akọrin
miran gba ami ẹyẹ Grammy lori awọn awo orin ti wọn gbe jade lọdun 2022.

Lara wọn ni Jack Harlow to
gbe awo orin “First Class” sita pẹlu Kendrick Lamar to se orin “Die Hard”.

Bakan naa ni Latto to se
awo orin “Big Energy (Live)”) pẹlu DJ Khaled to se awo orin “Beautiful” naa gba
ami ẹyẹ yii.

Ipele awọn akọrin
takansufe to dara julọ nidi orin “Rap” si ni wọn ti gba amin ẹyẹ naa.

Copyright: temsbaby/Instagram

Ta ni Temilade Openiyi ti ọpọ
eeyan n pe ni Tems?

Ọmọ bibi ilẹ Naijiria to
wa lati ẹya Yoruba ni Temilade Openiyi, adape orukọ rẹ naa si lo n pe ni Tems

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni
omidan Temilade Openiyi, ọjọ kẹtalelogun os Keje ọdun 1996 si lo dele aye.

Ile ẹkọ Dowen nilu Eko ni
Temilade lọ, ko to tẹkọ leti lọ kọ ẹkọ nipa imọ ọrọ aje ni fasiti kan lorilẹede
South Africa.

Mama rẹ nikan lo da
Temilade tọ dagba, to si bẹrẹ agbejade awo orin tiẹ nigba to pe ẹni ogun ọdun.

Gẹgẹ bi akọsilẹ BET ti sọ,
gbajumọ akọrin obinrin naa maa n nifẹ lati tẹti gbọ orin Asa, Adele, Lojayati
Zinloesky.

Lọkọ Kọkanlelọgbọn osu Kẹjọ
ọdun 2021 ni Temilade gba idalọla gẹgẹ bii akrin to gbajumọ fun BET.