Dapo Abiodun ṣé àbẹ̀wò sí CBN Ogun, bèèrè gbígbé bébà Naira síta

Dapo Abiodun laarin eeyan meji

Oríṣun àwòrán, Prince Dr. Dapo Abiodun – MFR/Facebook

Gomina Ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ṣe abẹwo si ẹka ileeṣẹ banki apapọ orilẹede Naijiria niluu Abeokuta, to rí rọ awọn osisẹ banki lati pese owo fun awọn araalu.

Gomina, ẹni to kọwọ rìn pẹlu abẹnugan ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Olakunle Oluomo ati eekan awọn osisẹ ìjọba ìpinlẹ naa ni wọn jọ ṣe abẹwo lọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu kejì ọdun 2023.

Nigba to n sọrọ lori opo ayelujara Facebook rẹ, Gomina Dapo Abiodun ni awọn ṣe abẹwo ọhun lati fi omijomitoro pẹlu awọn osisẹ banki apapọ lati wa ojutu si bí owo naira ko ṣe si nilẹ fun awọn araalu.

Gomina ni oun ti ransẹ si ìjọba oke lati mu ni ọkunkundun pe awọn araalu nilo owo lati fi se katakara wọn.

“Mo ni igbagbọ pe wiwasi ibi ẹka ileeṣẹ banki apapọ orilẹede Naijiria niluu Abeokuta ati ipade wa pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari niluu Abuja yoo wa ojutu si gbogbo rogbodiyan to waye lorilẹede Naijiria.

“Mo n fi asiko yii rọ àwọn eeyan ipinlẹ Ogun lati ṣe suuru, kí wọn si mọ pe gbogbo ọna ni ijoba n gba lati wa ojutu si ibi nǹkan ṣe wa lorilẹede Naijiria.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara da ọlọ́pàá sí báǹkì lórí ọ̀wọ́ngógó Náírà

Owó náírà tuntun

Oríṣun àwòrán, CBN

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti kéde pé àwọn ti da àwọn òṣìṣẹ́ àwọn sí àwọn ilé ìfowópamọ́ àti àwọn agbègbè mìíràn láti dènà àwọn jàǹdùkú láti dá wàhálà sílẹ̀.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ ọlọ́pàá Kwara, Ajayi Okasanmi ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara, Paul Odama gbé ìgbésẹ̀ náà látàrí fìnfìn tí wọ́n ń gbọ́ pé àwọn jàǹdùkú kan ti ń ko ara wọn jọ láti da ìpínlẹ̀ náà rú.

Okasanmi ní àwọn gbọ́ ìròyìn pé àwọn kan ti ń kó ara wọn jọ ní ìpínlẹ̀ Kwara láti lọ ṣe ìkọlù sí àwọn ilé ìfowópamọ́ kan nítorí wàhálà tí wọ́n ń kojú láti rí owó gbà ní báǹkì.

Ó ní èyí kò ṣẹ̀yìn bí àwọn kan ti ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní dá wàhálà sílẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní orílẹ̀ èdè yìí.

Ó fi dá àwọn ènìyàn lójú pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara kò ní fi àyè gba ẹnikẹ́ni láti da àláfíà ìpínlẹ̀ náà rú àti pé kò sí àyè fún àwọn tó bá fẹ́ tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀ ní Kwara.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Kwara náà fi kun pé ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò fimú gbóòórùn ọbẹ̀ ló láta nítorí náà kí gbogbo àwọn tó bá ní èrò láti hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ tọwọ́ ọmọ wọn bọṣọ ní kíákíá.

Láti bíi ọjọ́ méjì sẹ́yìn ni àwọn ènìyàn ti ń ṣe ìwọ́de ní àwọn ìpínlẹ̀ kan láti fi èrò wọn hàn lórí bí epo bẹntiróòlù àti owó Náírà ṣe wọn kankan ní ìgboro.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí