Buhari ṣèfilọ́lẹ̀ pápákọ̀ ojú omi l‘Eko láti kó ọjà wọlé láti òkè òkun

Pápákọ̀ omi Lekki Deep Sea

Oríṣun àwòrán, Others

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ pápákọ̀ omi èyí tó tóbi jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn Lekki Deep Sea Port.

Èròńgbà ìjọba ni láti pọkún ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà àti ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà láti pọkún owó tó ń wọlé lábélé.

Ní ọjọ́ Àìkú ni ọkọ̀ ojú omi tó kó ẹrù kọ́kọ́ balẹ̀ sí pápákọ̀ omi náà tí owó rẹ̀ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀ dọ́là ṣaájú ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Ajé.

Ní agbègbè Lekki Free Trade Zone, ìpínlẹ̀ Eko ni pápákọ̀ omi náà wà.

Gómìnà Babjide Sanwo-Olu nní òun gbàgbọ́ pé pápákọ̀ omi náà yóò pèsè iṣẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Eko, tí yóò tún máa owó gọbọi fún orílẹ̀ Nàìjíríà.

Ní oṣù Kejìlá ọdún 2017 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ kíkọ pápákọ̀ náà lẹ́yìn tí ìjọba àti iléeṣẹ́ The Lekki Port Investment Holding tọwọ́bọ àdéhùn ọlọ́dún márùndínláàdọ́ta.

Bákan náà ni èròńgbà wà pé pápákọ̀ omi láti fi kó ọjà wọ orílẹ̀ èdè yìí tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí yìí yóò mú àdínkù bá ọ̀wọ́n gógó tó máa ń bá owó tí wọ́n fi ń kó ọjà wọlé.

Dele Ayemibo sọ fún BBC pé òun rò ó wí pé ó yẹ kí wọ́n ti pèsè ọ̀nà ojú irin tàbí ọkọ̀ orí omi tí yóò máa gbé àwọn ọjà kúrò ní Eko láti mú àdínkù bá súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀.

Ayemibo ní ó pọn dandan láti pèsè ọ̀nà tó pọ̀ tí ọjà yóò máa gbà jáde kí ohun náà má ba à ní súnkẹrẹ fàkẹrẹ tó máa ń wáyé ní ọ̀nà Apapa.

Ààrẹ Buhari balẹ̀ sí Eko fún àkànṣe iṣẹ́ ọjọ́ méjì

Ààrẹ Buhari nígbà tó ń balẹ̀ sí Eko

Oríṣun àwòrán, Gboyega Akosile/Twitter

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Eko fún àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ méjì láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ àwọn àkànṣe iṣẹ́ kan ní ìpínlẹ̀ náà.

Ní nǹkan bíí aago mẹ́ta àbọ̀ ọ̀sán ni ààrẹ Muhammadu Buhari balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed ní ìpínlẹ̀ Eko.

Gómìnà Babajide Sanwo-Olu àti igbákejì rẹ̀, Obafemi Hamzat ló gba ààrẹ ní àlejò ní pápákọ̀ náà.

Àwọn tó tún kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú wọn ní gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun, gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Biodun Oyebanj, gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní Ekiti, Kayode Fayemi àti àwọn èèkàn mìíràn.

Lára àwọn àkànṣe iṣẹ́ tí ààrẹ yóò ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ ni pápákọ̀ omi Lekki, ilé iṣẹ́ ìrẹsì Imota, ọkọ̀ ojú irin tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ìpínlẹ̀ Eko yóò gbàlejò aarẹ Buhari, àwọn nǹkan ti Ààrẹ fẹ́ ṣe rèé

Buhari

Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti kede pe ipinlẹ naa yoo gba alejo Aarẹ Muhammadu Buhari  fun ọjọ meji ni ọsẹ to n bọ.

Kọmisọna feto iroyin ni ipinlẹ Eko Ọgbẹni Gbenga Omotoso, kede eyi lasiko apero kan ti o waye ni Alausa, Ikeja.

Omotoso ṣalaye pe abẹwo aarẹ ti yoo waye laaarin lọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun ati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kinni oṣu ọdun yii jẹ eyi ti Aarẹ yoo ti ṣe ifilọlẹ awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba Sanwo-Olu ti n ṣe  paapaa julọ akanṣe iṣẹ ni ibudo okun Lekki Deep Sea, ile iṣe ti wọn ti n fọ irẹsi ni Imot  ati akanṣe iṣẹ Reluwe ti ijọba ipinlẹ Eko  ṣe.

Kọmisọna fi kun pe Buhari yoo tun ṣe ifilọlẹ iṣẹ akanṣe aladani kan ni Apapa ati pe gomina ati iyawo rẹ, Dokita Ibijoke Sanwo-Olu ni yoo ṣiwaju awọn ti yoo ki Aarẹ  kabo.

Ijọba ipinlẹ Eko tun ti kede pe awọn opopona kọọkan ninu ìgboro Eko ati Lagos Island yoo wa ni titipa ni fun awọn ọjọ mejeeji ti aarẹ Buhari yoo fi maa ṣe awọn iṣẹ yii.

Wó àwọn ọ̀nà mìíràn to le gbà nígbà tí Àarẹ Buhari bá wà ní Eko

Ni ọjọ aje, ko ni si eto irinna lagbegbe ilẹ iṣẹ to n fọ iresi ni Imota Ikorodu(Lagos Rice Mill)ati agbegbe Ibudo Okun Lekki Deep Port.

Bakan naa ni ọjọ keji ko ni si aaye fun lilọ bibọ ọkọ lagbegbe ile ìtura Eko Hotels ni opopona Ahmadu Bello, J-Randle lọ si Broad street ati Marina lati aago mẹfa aarọ si aago mẹta ọsan.

Frederic Oladeinde ni awọn awako ko ni le gba Opona Ahmadu  Bello,Ademola Adetokunbo, ati Akin Adesola si afara Falomo kí wọn si gba opopona Alfred Rewane lọ si ibikíbi tí wọn ba n lọ.

Ẹwẹ, Kọmisọna naa ṣalaye awọn opopona miiran ti awọn awakọ le gba lojuna ati le din sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ku.

Awọn awakọ le dari si Onikan lati opopona Ozumba Mbadiwe ati Bonny Camp gba ori Afara Falomo tabi opopona Awolowo.

Bakan naa ni awọn awakọ lati opopona Awolowo lọ si Onikan, si Tinubu Square tabi awọn agbegbe to yi inu Eko ka le ko oju ọna Falomo lati jade si Alfred Rewane.

Fun awọn awakọ lati opopona King George V, ki wọn gba opopona Moloney si Obalende tabi ki wọn gba opopona Turton lọ si Moloney si Opopona Sandgrouse.

Fun awọn to n bọ lati Eko Bridge lọ si Marina kí wọn gba Elegbata si Ebute ero lọ si police post lati gun afara 3rd Mainland (Adeniji Adele) lọ si ibikíbi tí wọn  ń lọ.

Frederic fi kun pe gbogbo opopona to dari si awọn ọna ti aarẹ Buhari yoo gba kọja ni yoo wa ni titipa.