Gbogbo ọkàn mi ni mo fi sin Naijiria, n kò já ẹnikẹ́ni kulẹ̀ – Buhari

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe gbogbo ọkan oun loun fi sin Naijiria, oun ko si ja ẹnikẹni kulẹ.

Buhari lo sọ ọrọ naa lasiko to ṣabẹwo si aafin Emir ilu Bauhci, Rilwanu Suleiman Adamu, ni itẹsiwaju ipolongo ibo Aarẹ ati gomina fun ẹgbẹ oṣelu APC.

Aarẹ ni inu oun dun bi ọpọ ero ṣe wa pade oun eyii n tumọ si pe ọpọ araalu lo fẹran oun  denu.

Buhari sọ pe “Loorekoore ni mo maa n ṣabẹwo si awọn awọn Emir atawọn oloye lati fi ẹmi imoore mi han.”

“Mo fẹ sọ fun yin pe laarin ọdun 2003 si 2011, mo bẹ gbogbo ijọba ibilẹ wo, nigba ti mo n du ipo Aarẹ fun saa keji, mo ṣabẹwo si gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria.”

“Iye awọn eeyan to wa ki mi kaabọ pọ to bẹẹ ti ko si ẹni to le fi owo ra wọn, ibẹ ni mo ti pinnu pe mo maa fi gbogbo ọkan mi sin awọn ọmọ Najiria.”

 “Lati igba naa titi di akoko yii, mi o ja ẹnikẹni kulẹ rara.”

Nigba to n sọrọ, Emir Bauchi sọ pe ohun iwuri lo jẹ ni gbogbo igba ti awọn oloṣelu ba n bọwọ fun aṣa atawọn ori ade.

O ni irufẹ iwa bẹẹ n tumọ si pe wọn fun awọn ori ade ni iyi ati ẹyẹ to tọ si wọn.

Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ Buhari fun awọn iṣẹ idagbasoke to gbe ṣe ni ipinlẹ Bauchi.

Emir ọhun tun fi akoko naa dupẹ lọwọ Buhari fun bo ṣe yan ọmọ bibi ipinlẹ naa, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, gẹgẹ bii adari ajọ eleto idibo, INEC.