Wo ìdí pàtàkì mẹ́ta tí Russia se kọlu Ukraine

Ikolu Ukraine ati Russia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orisirisi idi ni awọn eeyan nn sọ pe o sokunfa ikolu Russia si Ukraine.

Bi awọn kan se gbagbọ pe imọtaraẹni nikan ti Aare Vladimir Putin naa ni awọn mii ni pe ọ̀rọ̀ ko ri bẹ́ẹ̀.

Lojobo, ọjọ́ kerinlelogun, osu keji, ọdun 2022 yii ni Russia kọ́kọ́ kọlu Ukraine.

Ariow ibugbamu to n dun to n jade lati Moscow lo gba igboro Ukraine kan lasiko naa.

Aare Vladimir Putin lo pasẹ ikọlu naa nini ikede lori amohunmaworan laago mefa din iseju marun un ni Russia ni eyi to jẹ́ aago meta din ni iseju marun un nuninu GMT aago agbaye.

Leyin eyi ni Aare Volodymyr Zelensky to je aare Ukraine kede lori amohunmaworan pe Aare Russia ko gbe aago ipe oun bẹ́ẹ̀ naa si ni ko pe oun pada.

Aare Putin ni ki won ko ohun eelo omo ogun ti wọ́n ri si awon ipinlẹ̀ ila oorun Yuroopu leyin odun 1997.

Idi meta pataki naa ni BBC to jọ yii:

1.Ibudo Alaafia

Orile-ede Russia gbagbo pe ibudo alaafia ti won n pe ni ‘Safe Zone’ni Ukraine jẹ́ fun awọn.

Eyi ko seyin pe Russia n fẹ́ ki awọn orile-ede to yii ka jẹ́ eyi ti awọn le fi ọkan tan pe alaafia jba nibẹ́ paapaa awon to wa ni ẹnu bode Russia.

Russia ko fẹ́ ki ọ̀tá kankan wọle si i lara nipase awon orileede to yii ka paapaa Ukraine.

Ojogbon ajọsepọ awon ilẹ̀ okeere ni Fasiti Virginia Tech, Gerald Toal sọ pé Ukraine da bi agbegbe ti wọn n pe ni ” Buffer Zone” fun Moscow to jẹ olu ilu Russia.. O ni ọpọ igba lo ti jẹ pe ẹkun Ukraine lo gba Russia silẹ nigba ogun agbaye kinni ati ikeji.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

2.Ukraine jẹ́ ibi itan manigbagbe, ibudo ẹ̀sin ati aṣa:

Saaju lọjọ kejila, oṣu keje, ọdun 2021 ni Aare Vlamir Putin ti fẹsun kan Ukraine ninu akọsilẹ rẹ pe Ukrain n ṣe ere gẹle to jẹ ki o di afojusun idiyele laarin Russia ati ilẹ Yuroopu.

Putin sọ pe aṣa, itan ati ẹsin pọ to pa Ukraine ati Russia papọ ni eyi ti oun ko fẹ ki ajoji tabi ika wọ Moscow nipasẹ Ukraine. O menuba awọn alalẹ ussia, Belaus ati Ukrainepapọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

3.Ukraine ni iṣẹ akanṣe ti Putin fẹ fi silẹ:

Kadi Liik to jẹ ọga agba onwoye iwadii nipa igbimo ilẹ okeere Yuroopu ati ajọṣepọ wọn si ara wọn to tun jẹ akọṣẹmọṣẹẹ nipa ajọṣepọ Russia ati awọn orilẹ-ede mii sọrọ lori eyi.

O ni pe ọpọ igba ni ihuwasi ati ipo Putin maa n dabi pe oun gangan lo n binu si iṣẹlẹ Ukraine lasiko to n ṣe aarẹ.

Kadi sọ eyi fun BBC Mundo ninu ifọrọwanilẹnuwo laipẹ.

O ni o n dun Putin pe igbiyanju rẹlati fi awọn to fẹran Russia si ipo ni Kyiv foriṣọnpon ti ko si bi eso ti o n reti nibẹ.

Ati pe Putin ni ero p-e iṣẹoun ko tii pari rara lori ọrọ Ukraine funra rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ