“Àìsàn tó ń ṣe Iyabo Oko ti ṣàkóbá fún ọmọ ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀”

Iyabo Oko

Ni ọjọ Isẹgun la mu iroyin wa fun yin nipa ipo ti ara osere tiata nni, Iyabo Oko de duro.

Gẹgẹ ba se mu wa fun yin, wọn ti fi mama naa silẹ nile iwosan kan to wa nilu Ibadan, to si ti n lọ gba itọju ninu ile rẹ.

Amọ o nilo dokita onimọ nipa tito egungun ati isan, ta mọ si Physiologist, eyi ti yoo mu ki eegun ara rẹ tubọ le si.

Nigba to n salaye ohun to mu ki aisan mama rẹ tubọ peleke si lẹyin ọdun marun to ti bọ lọwọ arun rọpa-rọsẹ lẹyin to gba itọju nilẹ India ati UK.

Ọkan lara ọmọ mama naa, salaye pe aimaa lọ fun ayẹwo ati itọju loore koore nile iwosan lo se akoba, ti aisan naa tun fi yọju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Mama mi kii lọ fun ayẹwo loore-koore ni aisan yii tun se yọju sita pada:

Ohun to sẹlẹ yii lo fihan pe aisan yii ko ba ti yọju rara to ba jẹ pe mama mi ni ọkọ ti yoo maa gbe kiri.

Ibi ti mama mi n gbe jinna pupọ si ile iwosan, o si maa n ro loju lati lọ nitori ko rọrun rara.”

Bakan naa lo fikun pe ọkada ni oun fi gbe Iyabo Oko de ikorita ile rẹ nigba to kọkọ ni aisan naa nitori ko si mọto to le gbe.

O salaye pe ikorita naa ni oun ti wa gba ọkọ to gbe lọ sile iwosan, ti wọn si sọ fun pe mama rẹ ti ni arun rọlapa-rọlẹsẹ, ta mọ si stroke lọdun diẹ sẹyin.

Ẹ dakun, ẹra mọto fun mama mi, ko le maa lọ sile iwosan loore koore:

Ọmọ Iyabo Oko wa n bẹ awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria pe ki wọn dakun da owo jọ lati ra mọto fun mama oun, ko le maa fi rin, ki aisan naa ma baa tun yọju mọ.

“O ti to ọdun marun sẹyin ti aisan stroke akọkọ yọju amọ mama mi ko fẹ ki ẹnikẹni mọ nipa aisan naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ẹgbọn mi gbe lọ silẹ China fun itọju nla, ti ara wọn si ya amọ o se ni laanu pe lẹyin eyi, aisan naa tun ti sọ ọ wo fun igba meji ọtọọtọ mii.

O ni a ko gbọdọ sọ fun ẹnikẹni amọ ni ọsẹ kan sẹyin ni aisan naa tun de, eyi to se akoba fun awọn ọmọ ika ẹsẹ rẹ.”

Aisan yii ti se akoba fun apa ati ẹsẹ mama mi:

Ọmọ Iyabo Oko fikun pe mama oun ti n gbadun bayii, o ti n sọrọ, to si n da awọn eeyan mọ.

Dokita tun ti wa fi da wa loju pe ta ba ri dokita to n na isan, to mọ isẹ rẹ nisẹ, idaniloju wa pe mama mi yoo le maa lo awọn ọmọ ika ẹsẹ rẹ.”

O wa mẹnuba pe awọn gbajumọ osere tiata bi Foluke Daramola, Iyabo Ojo, Mercy Aigbe ati Biodun Okeowo ni wọn ti se iranwọ owo fun mama oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ