Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Goodluck Jonathan ti sọ̀rọ̀ sókè, Ó ní wàhálà Nàìjíríà fẹ̀rẹ̀ gbẹ̀mí ìyá òun

Aworan aarẹ tẹlẹ Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Naijiria nigbakan ri, Goodluck Jonathan ti ṣalaye pe kii ṣe ọgbẹ diẹ ni aworan posi oun tawon eeyan kan n gbe kiri lasiko iwọde lori epo bentiro to waye lọdun 2012 da sara iya oun.

Aare Jonathan ṣalaye eyi ninu iwe rẹ tuntun to ṣẹṣẹ gbe jade to pe ni “My Transition Hours.”.

O ni “Iwode naa n tẹsiwaju. Ninu gbogbo ẹ, eeyan kan ti aanu rẹ ṣemi julọ ni iya mi to wa pẹlu mi ni ile aarẹ nigba naa.

Goodluck ni pe : “Ojojumọ lo n rii lori mohunmaworan bi awọn oluwọde ṣe n gbe fọto posi mi kiri ti wọn si n kọ akọle ‘sun re o’ sii lara.”

Aarẹ Jonathan ni ọpọlọpọ eeyan bii Alufaa agba inọ Winners Chapel, Bisọbu Oyedepo, alufa agba ijọ Anglican, Nichola Okoh atawọn mẹjọ miran lo n wa ba oun pe ki oun yi owo ori epo naa pada.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O fi kun un pe ohun to kọ oun lominu ju nipe awọn alatako nilu Eko ti ja iwọde naa gba debi pe wọn tun ko ẹgbẹ oṣiṣẹ ti ìjọba oun ti ṣalaye bi ọrọ ẹkunwo epo se hẹ mọ abẹ lati b’awọn darapọ mọ iwọde naa.