Adájọ́ faraya, ní òun le sún ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu láì ní gbèdéke ọjọ́ nítorí…

Nnamdi Kanu àtàwọn agbẹjọ́rò rẹ̀

Adájọ́ Binta Nyako ti dúnkokò láti sún ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu síwájú tí àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ kò bá tíì ṣetán láti ri pé ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.

Nyako tún mú ogúnjọ́, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 láti fi gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé bóyá kí àwọn agbófinró fi kélé òfin nú Nnamdi Kanu ní ilé rẹ̀, kí ó sì máa jẹ́jọ́ láti ilé rẹ̀.

Níbi ìgbẹ́jọ́ tó wáyé lọ́jọ́rù, ọjọ́ Kẹtàdínlọgún oṣù Kẹrin, agbẹjọ́rò Nnamdi Kanu, Aloy Ejimakor sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn kò ní àǹfàní láti máa rí Kanu tí àwọn bá fẹ́ bá sọ̀rọ̀ ní àhámọ́ tó wà.

“Wọn kìí fún wa láàyè ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ láti bá Nnamdi Kanu sọ̀rọ̀. Wọn kìí jẹ́ ka wọlé pẹ̀lú ohun ìkọ̀wé, wọ́n máa ń gba ohùn wà sílẹ̀ tí a bá ń sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà, nítorí náà lá ṣe ń rọ ilé ẹjọ́ láti fi ààyè gba Nnamdi Kanu láti wà ní àhámọ́ ní ilé rẹ̀,” Ejimakor sọ fún ilé ẹjọ́.

Ejimakor tún ní kí adájọ́ Nyako dá béèlì tí wọ́n fún Kanu ní ọdún 2017 padà pàápàá bí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Kanu sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀ ni kìí ṣe pé ó fẹ́ sálọ nítorí wọn gba béèlì rẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹjọ́rò fún ìjọba àpapọ̀, Adegboyega Awomolo ní kí ilé ẹjọ́ da àwọn ìbéèrè náà nù pé ilé ẹjọ́ ti gbọ́ wọn tẹ́lẹ̀ àti pé ilé ẹjọ́ kò ní àṣẹ láti lòdì sí ẹjọ́ tó ti dá tẹ́lẹ̀.

Awomolo ní àwọn tó ń jẹ́jọ́ ló yẹ kí wọ́n gbé ẹjọ́ wọn lọ sí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tí ìdájọ́ tí wọ́n gbà tẹ́lẹ̀ kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn.

Adájọ́ Nyako wá mú ogúnjọ́ oṣù Karùn-ún láti fi gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹjọ́ náà àmọ́ ó ní ìgbẹ́jọ́ gbọdọ̀ wáyé tí àwọn olùpẹjọ́ yóò sì pe ẹlẹ́rìí wọn wá.

Agbẹjọ́rò Kanu sọ fún adájọ́ pé àwọn kò gbèrò láti jẹ́ kí Kanu rojọ́ nítorí àwọn kò rí ààyè láti bá a sọ̀rọ̀ ní àhámọ́ tó wà.

Èyí bí adájọ́ Nyako nínú tó sì sọ fún agbẹjọ́rò Kanu pé òun le sún ìgbẹ́jọ́ síwájú láì ní ọjọ́ kan pàtó tí wọn yóò gbọ́ ẹjọ́ náà.

Ó ní tí òun bá sì sún ẹjọ́ náà sí ọjọ́ tí kò ní gbèdéke, ó túmọ́ si pé Nnamdi Kanu máa wà ní àhámọ́ fún ọjọ́ pípẹ́.

Lẹ́yìn náà ló sún ìgbẹ́jọ́ náà fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá kí Kanu àtàwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ lè jíròrò lórí ohun tí wọ́n bá fẹ́.

Nnamdi Kanu atawọn agbẹjọro rẹ

Nnamdi Kanu yóò tún fojú balé-ẹjọ́ lónìí

Nnamdi Kanu

Oni, Ọjọru ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin 2024 ni ajijagbara ẹya Igbo, Nnamdi Kanu yoo tun foju bale-ẹjọ l’Abuja.

Ẹsun meje ọtọtọ to da lori idunkooko ati idaluru ni Kanu to n beere ijọba Biafra fawọn ẹya Igbo n jẹjọ rẹ bayii.

Ẹsun bii mẹẹẹdogun ni ọga awọn IPOB naa n jẹjọ rẹ tẹlẹ nigba ti ijọba apapọ Naijiria gbe e wale lati oke okun ni 2020.

Atigba naa lo ti wa lahaamọ ajọ DSS.

Alaye awọn lọọya rẹ lori ailera ni pe iho wa lọkan Kanu to si nilo itọju.

Wọn ni eyi ko jẹ ko le ro ẹjọ rẹ bo ṣe yẹ lakata awọn DSS.

Wọn ni yoo daa bi wọn ba le yọnda rẹ lati gba itọju.

Kanu funra rẹ sọ pe DSS ko jẹ kawọn lọọya oun ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ

Ṣaa, Adajọ Binta Nyako, fagile mẹjọ ninu awọn ẹsun ti Kanu n jẹjọ rẹ, o ku meje.

BBC Yoruba yoo mu abajade igbẹjọ Nnamdi Kanu wa lẹyin ijokoo kootu lonii.

Iléẹjọ́ kọ̀ láti gba béèlì Nnamdi Kanu, dá a padà sí àhámọ́

Ni ọjọ kọkandinlogun, o’su Kẹta ni Kanu foju ba ile ẹjọ kẹyin lẹyin to ti wa ni atimọle ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati oṣu Kẹfa ọdun 2021.

Nigba ti o n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ Nyako paṣẹ pe ki igbẹjọ naa yara kiakia ju ti atẹyinwa lọ.

Bakan naa ni adajọ kepe igbimọ olupẹjọ lati mu ẹlẹri akọkọ wọn wa.

Ẹwẹ, agbẹjọro Kanu ko ṣai fi aidunnnu rẹ han si idajọ ileẹjọ.

Amofin Ejimakor ni o nira lati maa ba Kanu sọrọ ni atimọle DSS tori gbogbo ohun ti awọn ba fẹ sọ ni ajọ DSS yoo maa gbọ eleyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Ejimakor ni aṣọ kan naa lo si wa lọrun Kanu lati ọjọ yii, bo tilẹ jẹ pe ileẹjọ ti paṣẹ wi pe ki wọn paarọ aṣọ rẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, agbẹjọro ijọba apapọ, Adegboyega Awomolo (SAN), rọ ile ẹjọ lati yi ẹbẹ agbẹjọro Kanu sanu, eleyii ti ileẹjọ pada ṣe.

Amofin Awomolo(SAN) ṣalaye pe ajọ DSS ni ile iwosan ti Kanu ti le ṣe itọju ara rẹ.

Agbẹjọro ijọba tun sọ pe Kanu ti salọ tẹlẹ ri nigba ti ileẹjọ gba beeli rẹ lọdun 2017.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Ṣaaju ni ileẹjọ to julọ ni Naijiria ti kọkọ dajọ pe Nnamdi Kanu gbọjọ tẹsiwaju igbẹjọ rẹ nile ẹjọ giga lori awọn ẹsun ti ijọba apapọ fi kan an.

Ile ẹjọ to ga julọ yi idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to fagile awọn ẹsun ti ijọba apapọ fi kan Kanu danu.

Ninu idajọ rẹ, ile ẹjọ to ga julọ sọ pe Kanu to jẹ olori ẹgbẹ ajijagbara fawọn ẹya Igbo, IPOB, gbọdọ tẹsiwaju pẹlu igbẹjọ rẹ nile ẹjọ giga.

Ninu idajọ ile ẹjọ giga julọ eleyii ti adajọ Emmanuel Agim ṣe aadri rẹ, igbimọ igbẹjọ naa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun kuna lati paṣẹ pe Kanu ko ni lati lọ ile ẹjọ mọ tori lilodisofin bi ijọba apapọ ṣe ya wọ ile rẹ.

Ile ẹjọ ni lootọọ ni pe ọna ti ijọba Naijiria fi gbe Kanu pada wale lati orilẹede Kenya lodi sofin, amọ iyẹn ko ni pe ki Kanu ma lọ sile ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Ile ni Kanu le gbe ijọba lọ si ile ẹjọ lori bi ijọba apapọ ṣe gbe pada wa si Naijiria, amọ ko le sọ pe ki ile ẹjọ ma tẹsiwaju igbẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.