Òjò ńlá àti omíyalé ṣekúpa èèyàn tó lé ní 40

Aworan

Oríṣun àwòrán, Kenya National Highways Authority

O le ni ogoji eeyan to padanu ẹmi wọn ni orilẹede Kenya lẹyin ti omi adagun damu ya to si fa omiyale.

Ojo arọrọda to lagbara lo fa iṣẹlẹ naa, ti o si tun sọ ọpọlọpọ eeyan di alai ni ile lori lẹyin ti Damu to wa ni Kamuchiri ni iwọ oorun Kenya ya.

“Eeyan mejilelogoji lo ti ku bayii. Awọn mii si wa ni ẹrẹ.” Gomina Nakuru, Susan Kihika sọ fun AFP news.

O le ni ọgọrun-un eeyan ti iṣẹlẹ omiyale ti gba ẹmi wọn kaakiri Kenya ni oṣu to kọja.

Ikọ to n dola awọn eeyan ni lati ma hu ilẹ lati le ṣawari awọn eeyan to si wa laye ni abule kan ni Mai Mahiu, kilomita Ọgọta si olu ilu.

Oku eeyan mejilelogoji ni wọn ti ṣawari bayii, mẹtadinlogun jẹ ọmọde, Ọga ileeṣẹ ọlọpaa, Stephen Kirui sọ fun Reuters.

“Agbara nla ni omiyale ba de lati damu Kijabe, to si wo ọpọlọpọ ile ati ọkọ ayọkẹlẹ. A ko ri irufẹ eyi ri lati igba ti wọn ti bi wa si Mai Mahiu. Ọpọ eeyan lo ti di awati.” Olugbe, David Kamau sọ fun BBC.

Bakan naa ni ijọba ti sun ọjọ iwọle awọn akẹkọọ lorilẹede siwaju pẹlu erongba pe ojo nla mii si ma rọ gẹgẹ bii iwadi ṣe gbe sita.

O le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun un eeyan to ti di alai ni ile lori, ti ọpọ wọn si ni lati lọ ma sun si ile ẹkọ.

Iṣẹlẹ omiyale yii na wọpọ ni awọn orilẹede to sumọ Kenya bi Tanzania ati Burundi.

O le ni ọgọrun-un eeyan to ti padanu ẹmi wọn sọwọ omiyale lati oṣu kinni ọdun yii ni Tanzania.

Bakan naa ni Burundi, o le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan ti omiyale ti gba ile lọwọ wọn.