“Inú òkùnkùn birimù ni gbogbo Naijria yóò wà lóṣù mẹ́ta sí àsìkò yìí tí a bá kọ̀ láti fikún owó iná”

Power

Oríṣun àwòrán, @BryceJohanneck

Minisita fun ohun amuṣagbara, Adebayo Adelabu, ti kilọ pe o ṣeeṣe ki Naijiria wa ni okunkun birimu ti ijọba ko ba ṣe afikun owo ina ẹlẹtiriki.

Adelabu lo sọ ọrọ naa lasiko to yọju siwaju igbimọ awọn aṣofin lọjọ Aje, nibi to ti sọrọ lori eredi ti wọn ṣe fikun owo ina.

Igbesẹ naa lo waye lẹyin ti awọn aṣofin ọhun, ti sẹnetọ Enyinnaya Abaribe dari sọ pe awọn ko tẹwọgba afikun owo ina naa.

Adelabu ni “ẹka ina mọnamọna wa yoo dẹnukọlẹ ti a ba kọ lati fikun owo ina.

“Pẹlu nnkan ti a ni lọwọ yii, inu okunkun birimu ni gbogbo Naijria yoo wa ni oṣu mẹta si asiko yii ti a ba kọ lati ṣafikun owo ina.

“Afikun tuntun yii ni yoo gbe wa de ibi ti a n lọ, ọmọ Naijiria ni awa naa, a mọ pe ko rọrun.”

O sọ siwaju si pe Naijiria yoo nilo lati na o kere tan biliọnu mẹwaa dọla lọdọdun fun ọdun mẹwaa ki ina ijọba to le ṣenu ire.

Adelabu sọ pe “eyii ṣe pataki lati kọ awọn ohun ti a nilo lati ni ina to duro dede amọ ijọba ko ni irufẹ owo bẹẹ, eredi ree ti a fi nilo awọn aladani ti yoo kowo si ẹka ina mọnamọna.

“Ṣugbọn ki a to le fa awọn olowo nla nla wọle ina wa gbọdọ duro dede, ọohun ti a si le ṣe ni ki a fikun owo ina.

“Ti a ba tẹsiwaju lati maa gba N66 ti ijọba ko si san owo iranwọ lori ina, awọn oniṣowo naa ko ni wa.”

Lẹyin naa lo rọ awọn aṣofin ki wọn ṣatilẹyin fun ileeṣẹ mọnamọna ki nnkan le ṣe dede.

Ṣugbọn nigba to n fesi, olori igbimọ aṣofin ọhun, Enyinnaya Abaribe, sọ pe iya njẹ awọn araalu lọwọ yii.

Abaribe ni ki minisita ọhun wa ọna mii ti yoo fi yanju ọrọ naa dipo ko tun di ẹru lile le awọn ọmọ Naijiria lori nipa afikun owo ina.