Ààrẹ NLC tẹ́lẹ̀ Ayuba Waba ṣàlàyé ohun tó lè mú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ dẹ́kùn ìyanṣẹ́lódì báyì

Aworan Waba atawọn to n wọde

Oríṣun àwòrán, NLC/BBC

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria tẹlẹ, kọmuredi Ayuba Waba ti sọ wi pe ohun kan ṣoṣo to le yanju edeaiyede to n waye laarin ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba apapọ lori iyanṣẹlodi ati iwọde ti wọn n ṣe lọwọ

Ninu ọrọ to ba awọn oṣiṣẹ sọ nibi iwọde wọn ni gbagede unity Fountain nilu Abuja, Comrade Wabba ṣalaye pe o di igba ti ijọba apapọ Naijiria ba dẹkun kiko epo wọle lati ilẹ okeere ki gbogbo ohun to n run nilẹ yii to tan.

O ni niwọn igba ti Naijiria ba ṣi n ko epo wọle lati okeere dipo fifọ epo funrarẹ labẹle, ohun meji wa ti ko ni si ni agbara ikawọ rẹ; akọkọ ni iye ti wọn n ṣe paṣipaarọ owo ilẹ okeere ati iye ti wọn n ta epo yii ni ọja agbaye.

O ni eto mẹta ni ijọba bi lati gbe kalẹ lori ọrọ yii bi wọn ba fẹ ko ni iyanju, ilana kọmọnkia, ilana ọlọjọ diẹ ati ilana ọlọjọ pipẹ.

O ni ninu gbogbo ohun ti ijọba apapọ n gbe kalẹ bayii, ko tii si eyi to n fi oju jọ ilana ti yoo lee ba awọn eeyan orilẹede Naijiria pẹ dalẹ.

“Igbesẹ pajawiri ni ijọba apapọ kan n gbe. Awọn igbesẹ ti yoo kan mu itura ba araalu bayii na ni ti yoo si tun da wọn pada sinu oṣi ati irora wọn lọjọ iwaju.

‘Gbogbo ihalẹ ti wọn ṣe lori ileṣẹ ifọpo Dangote Refineries, pabo naa lo ja si’

Awọn oluwọde n ṣe iwọde

Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu bi awọn alaṣẹ ijọba nigba kan ṣe ko gbogbo ireti orilẹede yii si inu awo ileeṣẹ ifọpo aladani ti Dangote Refineries.

Waaba ni pẹlu gbogbo ileri ti ijọba ṣe ni igba naa pe bo ba ti bẹrẹ iṣẹ irọrun a de, sibẹ lẹyin ọpọlọpọ oṣu ti wọn ṣi i ko tii le bẹrẹ iṣẹ.

O ni ohun kan ṣoṣo to le yanju iṣoro yii lọwọlọwọ ni ki orilẹede Naijiria bẹrẹ si ni fọ epo labẹle.

“Ṣugbọn ohun to n han bayii ni pe pupọ awọn to wa nipo iṣejọba ni ko fẹ ki eyi ṣeeṣe. Ohun ti wọn n fẹ ni ki wọn maa ko epo wọle latoke okun nitori ohun ti wọn n ri jẹ nibẹ.”

O ni ohun ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n fẹ ni ki ijọba tu awọn ileeṣẹ ifọpo gbogbo to wa lorilẹede yii ṣe ki wọn si maa bẹrẹ si ni fọ epo labẹle.

NLC faraya lórí ọ̀rọ̀ Tinubu s’áráàlú, wọ́n ní ìyanṣẹ́lódì àwọn ṣì ń tẹ̀síwájú

Aworan aarẹ ati afihan ami ẹgbẹ oṣelu

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorileede Naijiria ti fapajanu lori ọrọ ti aarẹ Bola Tinubu ba araalu sọ nipa ipo ti ọrileede Naijiria wa bayii.

Wọn ni nṣe laarẹ Tinubu fi awọn nnkan to ṣe pataki silẹ ati pe awọn ọrọ ti ko kan araalu lo n mẹnu le.

Ninu atẹjade kan ti aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ, Comrade Joe Ajaero fi sita lọrọ yi ti jẹyọ.

Ẹgbẹ naa sọ pe ọrọ aarẹ kii ṣe esi taraalu lero ati wi pe ko jọ pe ọrọ yi mọ riri iru inira ati ijiya ti araalu n farada.

Ni pataki aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ Comrade Ajaero ni ọrọ awọn ileeṣẹ ifọpo Naijiria to dẹnukọlẹ ati atunṣe wọn lawọn lero pe aarẹ yoo sọ nipa rẹ.

”Ibẹrẹ gbogbo wahala yiyọ ẹkunwo taa n ri yi ko ṣẹhin aiṣẹ awọn ileeṣẹ ifọpo Naijiria.O ṣeni laanu pe lati oke de ilẹ ọrọ aarẹ Tinubu ko mẹnu ba atunṣe awọn ileeṣẹ ifọpo yi rara ati rara”

Aarẹ kọ lati ṣiṣọ loju awọn ọbayejẹ to wa nidi ojoro subsidy

Aworan atẹjade ti NLC fi sita

Oríṣun àwòrán, NLC

Ẹgbẹ oṣiṣẹ tun tẹsiwaju pe awọn ko ṣẹṣẹ maa sọ pe aarẹ ko ni afojusub lori nkan to ṣe pataki si araalu ati pe ọrọ rẹ to sọ tubọ fẹsẹ igbagbọ awọn yi rinlẹ.

Wọn ni aarẹ kọ lati darukọ awọn ọbayejẹ to n fa ẹjẹ ilu gbẹ nipa magomago idi ẹkunwo subsidy.

NLC sọ pe ko buyi kun aarẹ pe ko kan maa darukọ awọn alaburu yi bi igba pe alujọnu ni wọn.

”Ohun tawọn ọmọ Naijiria ro kan ni pe ki aarẹ sọ ifarajin rẹ lati mu awọn to lo n jale nipa ẹkunwo subsidy ko si ri pe wọn fi wọn jofin”

Lafikun, NLC sọ pe oju lasan lọrọ ti aarẹ sọ nipa ijiroro pẹlu awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lori owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ.

Ajaero ni gbogbo igba tawọn ba joko ijiroro pẹlu ijọba kii ṣi ifarajin pe wọn ṣetan lati mu gbogbo ileri wọn ṣẹ nipa afikun owo oṣu oṣiṣẹ.

Nitori eleyi o sọ petiti di akoko yi wọn ko ti ṣe ifilọlẹ igbimọ to yẹ ko ṣagbeyẹwo ọrọ afikun owo oṣu.

Iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹ gunle nkọ?

Aworan atẹjade ti NLC fi sita

Oríṣun àwòrán, NLC

Atẹjade ẹgbẹ oṣiṣẹ yi ko sọ boya aidunnu si ọrọ aarẹ yi yoo mu kawọn tẹsiwaju pẹlu iyanṣẹlodi lỌjọru.

Ohun pato taa ri ninu atẹjade naa ti aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ ni pe lopin igba tawọn ko ba ri pe ijọba n fi tọkantọkan ṣiṣẹ lati mu adinku ba inira araalu awọn ko ni jawọ nidi igbiyanju awọn.

Boya eleyi wa tunmọ si pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi taa n wi yi tabi bẹẹ kọ, a ko le sọ pato.

Ṣaaju asiko yi ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ti kede pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi lati fẹhonu han lori bi ara ṣe n ni araalu nitori yiyọ ẹkunwo epo bentiroo taa mọ si subsidy removal.

Wọn lawọn fẹ ṣe iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ yi titi ti ijọba yoo fi da awọn lohun lori ibeere wọn.

Awọn onwoye sọ pe o ṣeeṣe ki ikede aarẹ Tinubu lori awọn nkan amaye rọrun to kede jẹ ọna lati mu ki NLC jawọ nidi iyanṣẹlodi wọn.

Aarẹ sọ awọn igbesẹ kọọkan ati owo ti ijọba yoo na lati mu idẹkun ba araalu.

Amọ ninu ọrọ rẹ, ko si ohun to sọ ni pato nipa atunṣe awọn ileeṣẹ ifọpo Naijiria to ti dẹnukọlẹ to ọjọ mẹta.