A óò fi imú gbogbo àwọn tó ṣekúpa ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Eko dárin – Sanwo-Olu

Kazeem Abonde

Oríṣun àwòrán, Kazeem Abonde

Ijọba ipinlẹ Eko ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn janduku kan ṣe kọlu awọn agbofinro lagbegbe Ajao Estate, lasiko ti wọn lọ fi ṣikun ofun mu awọn ọlọkada labegbe naa.

Ninu atẹjade kan ti gomina, Babajide Sanwo-Olu fi lede, o ni oun ti ke si kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Akeem Odumosu lati fi imu gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu naa danrin.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹsan an ọdun 2021 yii ni awọn janduku naa ṣe ikọlu si awọn agbofinro ti wọn lọ fi papnpẹ ofin mu awọn ọlọkada lagbegbe naa, nibi ti wọn ti pa ọga ọlọpaa kan, CSP Kazeem Abonde ni ipakupa.

Sanwo-Olu sọ ninu atẹjade naa pe “Irufẹ iwa bayii jẹ ọna kan ti awọn eeyan yii gba lati tẹ ofin loju mọlẹ, a ko si ni faye gba iru rẹ lailai.”

“Mo ti ke si kọmiṣona ọlọpaa lati ri daju pe gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu naa ni ọwọ tẹ, ki wọn si foju wina ofin.”

O fi kun pe digbi ni ijọba oun wa lẹyin awọn agbofinro ipinlẹ Eko lẹnu iṣẹ wọn, ati pe ẹnikẹni to ba kọju ija si awọn agbofinro labẹ iṣejọba oun ko ni lọ lai jiya.

Sanwo-Olu ni oun ko ni la oju oun silẹ ki awọn aralu maa ṣekupa awọn agbofinro bii ẹni pa ẹran.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni araalu to ba mọ pe ọlọpaa ṣe oun ko gbọdọ fi ofin si ọwọ ara rẹ, ṣugbọn o gbọdọ gbe ọrọ naa gba ọna to tọ labẹ ofin.

Gomina naa fikun pe ko ni si aye fun araalu to ba fẹ maa ṣe idajọ lọwọ ara rẹ lati fi ipinlẹ Eko ṣebugbe.

Lẹyin naa lo ba awọn mọlẹbi oloogbe naa kẹdun, o si tun gbadura pe ki Eledumare tẹ oloogbe ọhun si afẹfẹ rere.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ