Ẹgbẹ́ IPOB ní òun kò lọ́wọ́ nínú ikú ọkọ Dora Akunyili, Chike

Chike Akunyili

Oríṣun àwòrán, others

Ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra, IPOB, ti kede pe oun ko lọwọ ninu bi awọn agbebọn ṣe pa ọkọ alaga ajọ NAFDAC nigba kan, oloogbe Dora Akunyili, Chike Akunyili.

Ọjọru ni iroyin jade pe awọn agbebọn pa ọjọgbọn Akunyili, awakọ rẹ, ati ẹṣọ alaabo rẹ kan, lasiko to n rinrinajo lati ipinlẹ Anambra si Enugu.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ IPOB fi sita, ẹgbẹ naa sọ pe oun ko lọwọ si awọn ipaniyan to n waye lasiko yii nilẹ Biafra.

O ni “awọn oloṣelu kan lo n fi orukọ IPOB boju, lati ma a pa awọn alatako wọn”.

“A ko ni ede aiyede kankan pẹlu Chike Akunyili, a ko si mọ ọ ri.”

IPOB sọ pe ki gbogbo awọn to n fi orukọ ẹgbẹ naa boju ṣe iṣẹ ibi jawọ ninu iwa naa.

Wọn ṣapejuwe iku Ọjọgbọn Akunyili gẹgẹ bi ipaniyan oṣelu, eyi to n waye lọwọlọwọ nitori eto idibo gomina ipinlẹ Anambra to n bọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bí àwọn agbébọn ṣe pa ọkọ mínísítà ètò ìròyìn tẹ́lẹ̀, Dora Akunyili

Awọ agbebọn kan ti yibọn pa dokita Chike Akunyili, to jẹ ọkọ minisita fun eto iroyin tẹlẹ, Ọjọgbọn Dora Akunyili.

Iroyin ni awọn agbebọn ọhun ṣekupa okunrin naa niulu Umuoji, to wa ni ijọba ibilẹ ariwa Idemili, ni ipinlẹ Anambra.

Ẹnikan to sumọ idilẹ oloogbe naa ṣalaye fun awọn akọroyin pe oloogbe ọhun ṣi wa nibi ipade awọn akẹkọjade faisiti ijọba apapọ to wa ni Nsuka, UNN, nibi ti wọn ti ṣe ayẹsi fun un.

Ẹni naa sọ pe “Mo ṣi wa pẹlu rẹ lanaa ni gbọgan Sheraton to wa nile ijọsin All Saints Cathedral niluu Onitsha.”

“Nibẹ ni a ti ṣe ipade awọn akẹkọjade faisiti ijọba apapọ to wa ni Nsuka nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti ṣe ayẹsi fun. un”

Ẹni naa ṣalaye pe oloogbe ọhun sọrọ daadaa nipa iyawo rẹ to jẹ minisita nigba kan ri, o si fi ẹbun owo 500,000 naira ta ẹgbẹ awọn akẹkọjade lọrẹ.

O ni “Koda, oun ati ọmọ rẹ okunrin ti orukọ rẹ n jẹ Obum ni wọn jọjọ wa nibi ipade naa.”

“A sin awọn mejeji lọ sidi ọkọ wọn, baba ati ọmọ naa si di mọ ara wọn ki awọn mejeji to pinya lọ sidi ọkọ wọn.”

Ẹwẹ, ẹlomiran to sunmọ ẹbi ọloogbe naa ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC.

Ẹni naa ni inu ibanujẹ nla ni awọn ẹbi oloogbe naa wa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ