‘Àyẹ̀wò ìdákọ́ńkọ́ mi gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa ìhùwàsí ọmọde fihàn pé Baba Ijesha fọwọ́ kan ọmọ Princess lọ́nà tí kò tọ́’

Baba Ijesha ati Princess

Oríṣun àwòrán, Baba ijesha, Princess

Onimọ ijinlẹ kan nipa ihuwasi ọmọde ti sọ pe lootọ ni Baba Ijesha fọwọ kan ọmọ Princess lọna ti ko tọ nigba ti ọmọ naa wa ni ọdun meje.

Onimọ ijinlẹ naa, Anike Olabisi lo sọ ọrọ ọhun lasiko to n jẹri niwaju adajọ Oluwatoyi Taiwo to n gbọ ẹjọ ifipabanilopọ ti wọn fi kan Baba Ijesha loṣu kẹrin ọdun yii.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ni ọmọ naa ṣalaye fun oun ninu ifọrọwanilẹnuwo idakọnkọ kan pe igba meji ọtọtọ ni olujẹjọ naa fọwọ kan ọmọ ọhun ti ọmọ naa ko si le ke sita lasiko naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Anike Olabisi sọ pe iwadii finifini ti oun ṣe fi han pe ko si irọ ninu ọrọ ti ọmọ naa ṣo fun oun, ati pe awọn onimọ ijinlẹ miran ti gbe iwadii oun yẹwo, wọn si fi ontẹ lu pe o yanranti.

Wayi o, ile ẹjọ giga naa ti wa gba iwadii na wọlẹ gẹgẹ bii ọkanlara awọn “exhibit” ti wọn yoo lo ninu igbẹjọ ọhun bo ṣe n lọ lọwọ.

Adajọ Oluatoyin Taiwo ti wa sun igbẹjó naa si ogunjọ ati ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 yii.

ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Mo sún ìgbẹ́jọ́ yìí láàrin Princess àti Baba Ijesha síwájú di 21/10/2021 torípé …- Adájọ́

Ile Ẹjọ

Adajọ to n dari igbẹjọ laarin gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba to ti ń jẹjọ lórí ẹ̀sùn if ipa bá ọmọdé lopọ fun oṣù bíi melo kan báyìí, Olanrewaju Omiyinka tí orúkọ ori itage rẹ n jẹ Baba Ijesha ati Princess ti kede pe igbẹjọ tun di ọjọ mii.

Igbẹjọ naa bẹrẹ lowurọ ọjọ Iṣẹgun nile ẹjọ giga ipinlẹ Eko ẹka ti wọn ti n gbẹjọ akanṣe nipa ifipabani lopọ laarin Princess ati Baba Ijesha.

Lyin gbogbo ẹri ti wọn gbe wa ati agbeyẹwo ni adaj ni idajọ naa ti sun siwaju di ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹwa ọdun 2021.

Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba to ti ń jẹjọ lórí ẹ̀sùn if ipa bá ọmọdé lopọ fun oṣù bíi melo kan báyìí, Olanrewaju Omiyinka tí orúkọ ori itage rẹ n jẹ Baba Ijesha kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ lónìí ọjọ́ kejidinlogbon oṣù Kẹ̀sán.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣáájú nigba to farahan kẹ́yìn, ile ejo kéde isunsiwaju igbejọ naa si ọjọ́ Aje ọjọ́ kẹtadinlogbon àmọ́ nígbà ti BBC Yoruba kan si awọn ti ọ̀rọ̀ kan fun aridaju, o tẹ wa lọ́wọ́ pe o tun di ọjọ kejidinlogbon.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọrọ naa gbona janjan lati igba ti Princess the Commediene to jẹ alagbatọ ọmọdebinrin ti wọn ni Baba Ijesha fẹ́ ba ṣe àṣemáṣe pariwo sita pe afẹ́fẹ́ ti fẹ́, àwọn ti rí furọ adìyẹ, eyi si ni ọpọlọpọ àwọn òṣeré akẹgbẹ́ wọn naa bẹ̀rẹ̀ si ni ja lè lori ti onikaluku wọn ń to sẹ́yìn ẹni ti wọn ro pe o yẹ ko gba idalare.

Baba Ijesha nile ẹjọ
Princess ati Iyabo Ojo
Princess

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ninu oṣu kẹrin ọdun yii ni wọn Ọlọpaa gbee ti wọn si kọkọ gbee lọ si ile ẹjọ, pẹlu awọn ẹri ti Princess gbe wa pe o fipa ba ọmọ ti oun n gba tọ lopọ, wọn juu si atimọle nibi to wa fun oṣu kan gbako ki wọn to tun tẹsiwaju.

Lasiko yi, ile ẹjọ gba beeli rẹ amọ ko gunmọ to lo ṣe lo ọgbọn ọjọ lọgba ẹwọn ki wn to tun gbe ẹjọ rẹ lọ si ile ẹjọ Majisireeti Yaba nibi ti wn tun ti dari ẹjọ rẹ lọ si ile ẹjọ giga ti ipinlẹ Eko fun awọn akanṣe ẹsun.

Baba Ijesha nile ẹjọ

Ẹwẹ, ninu awọn igbẹjọ́ to ti waye sẹ́yìn, wọn ti gbọ láti ẹnu olupejọ, Princess; adajọ ti tẹ́wọ́ gba àwọn ẹri bẹẹ si ni wọn fun Baba Ijesha laye lati béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Princess lórí àwọn ẹri to ko wa.Pẹlu ìwádìí wa, lonii ó ṣeéṣe ki adajọ gbọ ọ̀rọ̀ latẹnu igun mejeeji tọrọ kan.

Wọn gbe Princess naa sinu koto ẹjọ ti wọn si fọrọ waa lẹnu wo. Lasiko idahun Princess lo ti jẹ ka mọ iru ibaṣepọ to wa laarin oun ati Baba Ijesha.

Princess ṣalaye bi Baba Ijesha ṣe dẹnu ifẹ kọọ titi di igba ti wọn pada di ọrẹ to ṣe di pe Baba Ijesha maa n lọ sinu ile rẹ.

Princess nile ẹjọ

Lara ẹri to mu wa ni fidio kan to tan kaakiri lasiko kan tẹẹ ba ranti ninu eyi ti Baba Ijesha ti n gbiyanju lati rin ọmọdebinrin ọhun ni kake ati awọn ere to n ṣaaju ibalopọ.

Nitori pe ọmọde ni labẹ ofin, adaj le gbogbo ẹni ti ẹj ko kan jade to fi mọ awọn oniroyin lasiko yii amọ o gba fidio naa wọle ggẹ bi ẹri (Exhibit A).

Princess nile ẹjọ

Nigba ti iṣlẹ yii ṣẹlẹ gangan, fidio kan naa jade ti Baba Ijesha ti n bẹ Princess pe eṣu lo lo oun ko si dari ji oun.

Ẹwẹ, ninu oniruuru ẹsun marun ti ile ẹjọ kọ sita bayii pe wọn fi kan Baba Ijesha ni pe o fipa ba ọmọ lo pọ, o fipa ba ọmọ lopọ nipa fifi nkan ọmọkunrin rẹ sinu nkan ọmọbinrin naa, ẹsun pe o tun fẹ fipa ba ọmọ lo pọ.

Gbogbo ẹsun yii si ni Baba ijesha ni oun ko jẹbi wọn. Ijiya to tọ si iru ẹsun yii bi wọn ba pada rii pe o jẹbi ni yala ẹwọn ọdun mẹta si meje fun awọn ẹsun kan ati ẹwọn gbere fun ẹkan lara awọn ẹsun naa.