“A ò lè sọ pàtó ibi tí Raheem Adedoyin wà báyìí”; “Àmọ́ ẹ mọ̀ nígbà tí ọlọ́pàá kò tíì wá a”- Agbẹjọ́rò Adedoyin àti ti ìdílé Timothy takurọ̀sọ

Adedoyin ati Raheem ọmọ rẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

BBC Yoruba kan si agbẹjọro idile mejeji ti ọrọ kan bayii lori ẹjọ iku Timothy Adegoke lati mọ iha ti idile mejeji kọ si awọn iroyin to n jade lẹnu ọjọ mẹta yii nipa ẹjọ naa.

Bi agbẹjọro fun idile Oloye Raheem Adedoyin, agbẹjọro Abiodun Williams ṣe sọ fun BBC Yoruba pe nkan ti oun ko ba tii ri gẹgẹ bii amofin, oun kii ki ọrun bọ ọ, lọgan ni agbẹjọro idile oloogbe Timothy Adegoke naa han ibeere yii lẹnu akọroyin wa to fọrọ wa a lẹnu wo.

Agbẹjọro ẹbi Adedoyin: Awa o tii ri iwe ile ẹjọ, ti a ba ti rii, a maa fesi sii torinaa ahesọ lasan la n gbọ lori ayelujara.

Abiodun Williams ni bo ṣe jẹ pe ilu Abuja ni ile iṣẹ ọlọpaa ti n ṣakoso ẹsun iku Timothy, nkan to yẹ ki ile ẹjọ sọ fun awọn ni pe ki wọn ke pe awọn ati pe Abuja kan naa ni Oloye Adedoyin wa, ti wọn ba fẹ ko tẹ lọwọ, wọn a jẹ ko mọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ni tiwa, ahesọ ọrọ lasan ni pe ile ẹjọ kede pe wọn kede Raheem Adedoyin gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa tori emi gẹgẹ bi agbẹjọro idile Adedoyin pe mi o tii ri ẹda iwe ile ẹjọ yii. Mi o s pe wọn ko wa Raheem o amọ emi o tii ri iwe ile ẹjọ”.

Agbẹjọro ẹbi oloogbe Timothy Adegoke: Arabinrin Noim Adekilekun sọ fun BBC Yoruba pe ilana wo lo ku ti ẹni kankan fẹ ki ile ẹjọ tẹle. “Emi o mọ ibi to ti ka iwe ẹjọ tirẹ o ati pe ṣe ti wn ba fẹ kede eeyan kan gẹgẹ bii ẹni ti wọn n wa, ṣe ki wọn ṣẹṣẹ kọwe ranṣẹ sii ni? Amọ mo fẹ fi daa yin loju pe ile ẹjọ ti kede Raheem Adedoyin gẹgẹ bii ẹni ti wọn n wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣe lootọ ni pe Raheem Adedoyin sa lọ, ibo gaan lo wa bayii?

Agbẹjọro ẹbi Adedoyin: Agbẹjọro Abiodun ṣalaye pe nigba ti ẹjọ yii ṣẹṣẹ bẹrẹ ti wọn n fi panpẹ ofin mu awọn afurasi, ko sẹni to lọ mu Raheem Adedoyin, bẹ o si wa ni ilu Ile Ife.

“Amọ lọwọ baa ṣe n sọrọ yii, mi o le sọ pato ibi ti Ọgbẹni Raheem ọmọ Oloye Adedoyin wa ṣugbọn nigbakuugba to ba jẹ pe wọn n wa a ko wa jẹjọ, awa agbẹjọro fọwọ sii pe ko yọju si wọn ko wa jẹ wọn ni oo”.

Agbẹjọro ẹbi oloogbe Timothy Adegoke: Ṣebi agbẹjọro wọn naa lo mọ ibi to wa nigba ti wọn ko fi kede rẹ bii ẹni ti wọn n wa, kilode ti ko le sọ ibi to salọ nisinsiyii fun ọlọpaa?

Agbẹjọro Noim ni teeyan ba fẹ ran idajọ ododo lọwọ, ojuṣẹ agbẹjọro wọn ni lati gbe ohunkohun ti ile ẹjọ ba kede sita. “Bawo ni agbẹjọro wọn o ṣe ni mọ ibi to wa nisinsiyii nigba to gbọ pe wọn n wa a bayii.

O tun ṣalaye pe ṣe agbẹjọro naa ba wọn wa papọ nibi ti wọn wa lọjọ naa ni to fi mọ pe wn o si nibẹ. “Ṣebi nkan ti Adedoyin ba sọ fun un ni yoo sọ”.

CCTV Kamẹra

Lori ọrọ Kamẹra CCTV tawọn eeyan n sọ pe o ṣafihan bi Raheem ati Baba rẹ ṣe dari awọn to gbe oku Timothy sita ninu ile itura agbẹjọro wọn ni irọ to jina si ootọ ni o.

“Lakọkọ, oloye Adedoyin ko si ni ile itura lọjọ naa bakan naa si ni Raheem ko si ni ile itura ọhun lọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ

Lori iroyin to ti pẹ kan to jade pe idile Adedoyin lọ n fi owo bẹ idile Timothy lati jẹ ẹjọ naa mọlẹ, agbẹjọro wọn ni irọ patapata gbaa ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Mo ti sọ ọ lori eto ori rẹdio kan mo si tun n tun un sọ pe Oloye Adedoyin ko ran ẹnikni si idile Adegoke lati kasẹ ọrọ yii nilẹ”.

O ni bi ẹnikẹni ba wa mọ ẹni to wa si ile Adegoke lati fi owo bẹ wọn ki wọn fi orukọ rẹ sita ki ijba le foju wo o ki wọ ma kan sọ ahesọ ọrọ.

O ni idi idajọ ododo ni awọn wa. “Ọgbẹni Timothy Adegoke kii ṣe eweb ọja ta o maa duna dura le lori, eeyan gidi ni”.

Agbẹjọro Noim to jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro idile Adegoke jẹ ko di mimọ pe ọlọpaa n ṣe nkan ti wọn le ṣe gbogbo awọn ti ọrọ kan si lo n ko ipa tiwọn.

Agbẹjọro Maxwell ti wa pe oniroyin kan to gbajumọ ni Ibadan, Hamzat Oriyomi sita pe ko wa fi fidio to n sọrọ nipa rẹ han sita amọ pe ko tii ṣe bẹẹ titi di asiko yii.

O ni bi ko ba gbe e jade, awọn yoo ba a ti ọwọ ofin bọ ọ o.

Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, @NatashaOfLagos

Esi wa si Hamzat Oriyomi

Ọkan lara awọn agbẹjọro to n ṣoju Ramon Adedoyin, to ni ile itura Hilton ti Timothy Adegoke ku si ni Ile Ife ti ni ki awọn eeyan má naani iroyin to n lọ ni igboro pe ẹrọ ayaworan CCTV kan ti tu aṣiri bi wọn ṣe pa oloogbe naa nile itura ọhun.

Agbẹjọro naa, Abiodun Williams sọ pe iroyin ohun ti akọroyin kan, Oriyomi Hamzat n gbe kiri ko ni ootọ kankan ninu.

Williams sọ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti Hamzat yoo gbiyanju lati ba orukọ Adedoyin jẹ loju awọn araalu, paapaa lẹyin ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni ileeṣẹ ọlọpaa ko tii fi atẹjade kankan sita nipa ibi ti wọn ba iṣẹ de, ati pe Adedoyin funra rẹ ko si nile itura naa lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, nitori naa, o ṣoro fun lati wa ninu aworan CCTV ti wọn n sọ nipa rẹ.

Agbẹjọro naa ni “A ti gbọ pe ọgbẹni Hamzat ti n sọ oniruru ọrọ kobakungbe lodi si Adedoyin ati mọlẹbi rẹ lati igba ti Timothy Adegoke ti jade laye.”

“A fẹ fi akoko yii sọ fun awọn araalu pe ki wọn ma naani irọ ti okunrin naa n pa fun wọn ṣugbọn ki wọn duro de esi abajade iwaddi awọn ọlọpaa lati mọ bi ọrọ iku oloogbe naa ṣe jẹ.”

“Imọran wa si Hamzat atawọn eeya mii to ba mọ ohunkohun nipa iku Adegoke ni pe ki wọn tọ ileeṣẹ ọlọpaa lọ ki iwadii wọn le ya.”

Agbẹjọro naa fi kun pe ile ẹjọ nikan lo le kede pe afurasi kankan jẹbi ẹsun ti wọn ba fi kan, nitori naa ki Hamzat atawọn eeyan mii to ba n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri, tabi ti wọn ba n ṣedajọ laye ara wọn lọ sinmi agbaja.

O pari ọrọ rẹ pe kii ṣe ori ayelujara ni o tọ lati maa kede pe afurasi jẹbi ẹsunkẹsun lai gba ile ẹjọ laye lati ṣiṣẹ wọn.

Ṣaaju ni Hamzat, to jẹ akọroyin, ajafẹtọ ati sọrọ-sọrọ ori redio ti kọkọ kede loju opo Facebook rẹ pe ọwọ oun ti tẹ aworan CCTV kan, eyii to ṣafihan bi Adedoyin atawọn oṣiṣẹ rẹ kan ṣe pa Adegoke nile itura naa lọdun 2021.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ