Kìí ṣe ilẹ̀ Afíríkà ni mo wà nígbà tí mo kọ́kọ́ wá sílé ayé – àṣírí ọ̀rọ̀ tuntun rèé lẹ́nu Mummy G.O

Mummy GO

Ajihinrere obinrin Funmilayo Adebayo, ti ọpọ mọ si Mummy GO ti sọ pe lootọ ni oun ti kọkọ lo ẹgbẹrun ọdun din mẹwaa nigba ti oun kọkọ wa sile aye ki oun to pada wa lati ṣe atunṣe iwa ibi to ti wu sẹyin.

Mummy GO lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba ni esi si awọn iwaasu rẹ to n mi ori ayelujara titi.

Gẹgẹ bii oun to sọ, o ni to ba le ṣeeṣe ki Elijah pada wa ninu bibeli ni awọ Johanu onitẹbọmi, ko yẹ ko jẹ kayeefi fun awọn eeyan pe oun le pada wa sile aye lati wa ṣe atunṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni nitori gbogbo iṣẹ ibi ti oun ti ṣe ṣaaju ni Ọlọrun ṣe ran oun pada wa sile aye lati ṣe atunṣẹ rẹ.

Ajihinrere naa ṣalaye pe kii ṣe ilẹ Afrika ni oun wa nigba ti oun kọkọ wa sile aye ṣaaju, bẹẹ si ni ọpọ awọn ti wọn jọ wa nile aye lọpọ ọdun naa ṣeyin ni wọn ṣi wa nile aye bayii.

“Mo ti kọ́kọ́ lo ọdún 990 nílé eyé kí ń tó padà wá láti ṣe àtúnṣe”.

Ni ti ọrọ kaadi MasterCard, Mummy GO ni oun ko sọ pe awọn to n lo MasterCard yoo lọ si ọrun apaadi, ṣugbọn ohun ti oun sọ ni pe imọ ẹrọ yoo tẹsiwaju ti awọn eeyan yoo si le maa gba owo nibikibi ti wọn ba wa kaakiri agbaye.

O ṣalaye siwaju si pe imọ ẹrọ naa ni yoo wa titi ti awọn olugbe aye yoo fi wọ inu ijọba aṣodi si Kristi.

Arabinrin Funmilayo Adebayo tun ṣalaye sii pe yoo ṣoro fun awọn to n ṣiṣẹ apanilẹrin ori itage lati ri ọrun wọ nitori pe wọn maa n pa irọ pupọ nidi iṣẹ wọn.

Mummy GO ni gbogbo ọrọ ti oun n sọ kii ṣe lati ṣe idẹyesi ẹnikẹni, ṣugbọn awọn ọrọ naa lo ni gbongbo ninu bibeli.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni “Wọn ni iwaasu mi le, ṣugbọn ọrọ inu bibeli naa le o… ẹni ti iwaasu mi ko ba tẹ lọrun ko ju bibeli sọnu.”

Lara awọn nnkan mii ti obinrin naa tun sọ fun BBC Yoruba ni pe oun ni ẹni akọkọ to ṣe ayederu irun ninu isalẹ omi.

O ni “Ki n to fi aye mi fun Jesu ninu isalẹ omi, emi ni mo kọkọ ṣe ayederu irun.”

Ni ti awọn ọmọ ijọ rẹ, o ni tọkan-tọkan ni wọn fi n gba iwaasu oun.

Bo tilẹ jẹ o sọ pe ọpọ awọn ọmọ ijọ naa lo kọkọ maa n salọ lẹyin ti wọn ba sọ pe ọrọ naa ti le ju, amọ lẹyin o rẹyin, ọpọ eeyan lo ti n yipada nipasẹ iwaasu oun.

O pari ọrọ rẹ pe ki awọn eeyan fi aye wọn fun Jesu ki wọn le ri ijọba ọrun wọ.

Lẹyin naa lo bẹ awọn eeyan ki wọn dẹkun ati maa sọ ohun ti oun ko sọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ