Ìgbà márùn ùn ọtọ́ọ̀tọ tí Nàìjíríà àti Egypt kojú lórí pápá ní Afcon

Aworan Mohammed Salah ati Kelchi Iheanacho

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ ree bi ana ti wọn kede pe Naijiria ati Egypt to fi mọ Guinea Bissau ati Sudan ni yoo jijọ waako ni isọri kẹrin Afcon2021.

Igbaradi ti waye, ipalẹmọ naa si ti tẹle, ohun to kan bayi ni ki Naijiria ati Egypt ṣide ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn ni isọri yi ninu idije Afcon ni Cameroun.

Awọn mejeeji ki ṣe alejo ara wọn ninu idije Afcon to si ṣe pe igba mẹwa apapọ ni wọn ti jijọ gba ife ẹyẹ idije yi.

Egypt wa si idije yi pẹlu agbabọọlu atamatase to n yọ eruku lala lọwọ yi, eyi tii ṣe Mohammed Salah.

Ni ti Naijiria, awọn ogbontarigi agbabọọlu wa ninu ikọ Super Eagles bi Kelechi Iheanacho.

Victor Osimhen ti ko ba soju Naijiria ko ribi wa nitori pe o ko arun Covid-19.

Afihan atẹ isọri Group D

Ninu isọri ti wọn jijọ wa yi, oju wa lara awọn mejeeji gẹgẹ bi alagbara meji to yẹ ko jade ni isọri naa.

Ki eleyi to waye, wọn gbọdọ figagbaga lonii lati mọ ẹni ti yoo tiẹ kọkọ jaweolubori.

Igba marun un ọtọọtọ ree ti awọn mejeeji ti gbena woju ara wọn ati nkan manigbagbe to waye nigba naa.

Onuachu gba bọọlu sawọn Egypt lẹyin iṣẹju aya mẹsan pere

Paul Onuachulo jẹ fun Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Naijiria 1 Egypt 0 (2019) – O ti n sunmọ ọdun mẹtaa bọ bayi ti Paul Onuachu gba bọọlu si awọn Egypt ninu ifẹswsẹ ọlọrẹjọrẹ kan.

Naijiria bori pẹlu goolukan si odo,

Goolu taa n wi yi lawọn eeyan sọ pe o jẹ eleyi ti o yara julọ ti Eagles jẹ ninu itan.

Papa Iṣere Stephen Keshi to wa ni Asaba ni wọn ti koju ara wọn.

Ọkẹ aimọye ololufẹ Super Eagles tu yaya wa wo wọn ni Kaduna

Naijiria1 Egypt 1 (2016)

Ipade yi jẹ ọkan ninu awọn manigbagbe ikoju laarin awọn mejeeji pẹlu bawọn eeyan ti ṣe tu yaya wa wo ikọ Super Eagles.

Wọn koju Egypt lara ifẹsẹwọnsẹ lati le fi kopa ninu idije Afcon taa mọ si 2017 qualifiers.

Nigba taa n wi yi, Etebo Oghenekaro lo kọkọ ja oju egbo ki Mohammed Salah to da ọgbẹ naa pada lọkan awọn ololufẹ Eagles ni iṣẹju ipari ipade naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Naijiria fidirẹmi, wọn kuna lati pegede fun Afcon

Mohamed Saleh ati Stanley Amuzie

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Egypt 1 Nigeria 0 (2016)

Ifẹsẹwọnsẹ yi ni abala keji eleyi ti wọn ti ṣaaju gba ni Kaduna ti wọn si gba ọmi.

Ipadabọ abija Egypt si Cairo lo mu ki Naijiria fidirẹmi nigba ti Ramadahna Sobhi jẹ goolu ni iṣẹju mejilelọgọta ifẹsẹwọns naa.

Ifiudirẹmi yi lo mu ki Naijiria kuna lati kopa ninu idije Afcon 2017 toun ti pe awọn ni wọn gba kẹyin ni 2013

Egypt gbẹyin wa lati doju Eagles bole

Egypt 3 Nigeria 1 (2010)

Lọdun taa n wi yi,awọn ikọ orileede mejeeji yi pade ni idije Afcon 2010.

Nigba yi ni Egypt lawọn ogbontarigi agbabọọlu bi Ahmed Hassan ati Mohammed Zidane.

Isọri ẹlẹkẹẹta ni wọn jijọ wa.

Ahmed Hassan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Chinedu Obasi lo kọkọ jẹ goolu fun Naijiria ṣugbọn bi ẹni tana wa iya lo jẹ nitori Egypt fi da goolu meji pada fun wọn.

Egypt lo pada leke isọri yi lọdun 2010

Rashidi Yekini lewaju Naijiria ti wọn si pegede

Rashidi Yekini in action for Nigeria at the Africa Cup of Nations

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigeria 1 Egypt 0 (1990)

Ni 1990 Naijiria ti Egypt pade ni isọri kẹta ninu idije Afcon Algiers 90.

Lọtẹ yi, awọn Super Eagles lo bori.

Oloogbe Rasidi Yekini lo jẹ goolu kan ṣoṣo ifẹswọns naa ni iṣẹju kẹjọ ti wọn d’ori papa.

Papa iṣere nla Stade Juliet ni Algiers ni ipade naa ti waye.