$4.1bn ta fẹ́ yá, àkànṣe iṣẹ́ ta fẹ́ fí ṣe yíká Naijiria rèé – Ìjọba àpapọ̀

Eyawo

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba aarẹ Buhari ti gbe alakalẹ bi wọn ṣe fẹ lo owo to le ni biliọnu mẹrin dọla ti wọn fẹ ya lọwọ banki agbaye ati orilẹede miran.

Wọn si tun salaye awọn ipinlẹ ati ileeṣẹ ijọba ti yoo jẹ ọla ẹyawo yii.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn eniyan ṣe faraya lẹyin ti aarẹ Buhari kọ iwe si Ile Igbimọ Aṣofin agba lati fi aṣẹ si ibeere ijọba to fẹ ya iye owo to to $4.054bn ati €710million, to fi mọ owo iranwọ to to $125m.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ, ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki si aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Mallam Garba Shehu fisita, o ni awọn fẹ lo ẹyawo naa lati ṣe awọn iṣẹ akanṣe papa awọn ileeṣe ti yoo jẹ anfaani fun awọn ọmọ Naijiria.

Garba Shehu ni awọn iṣẹ akanse yoo kan ẹka irinna, ina ijọba, eto ilera, eto ọgbin, eto ẹkọ ati awọn ẹka miran to pọn dandan si idagbasoke orilẹede Naijria kaakiri awọn ipinlẹ to wa ni Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Iṣẹ akanṣe marundinlogun to kaakiri ẹkun mẹfẹẹfa lorilẹede Naijiria ni owo ẹya naa yoo wulọ fun.”

”Aarẹ Buhari si ti kọwe si kọwe si Ile Aṣofin agba fun iye owo to le ni biliọnu mẹrin owo ilẹ okeere naa, ti wọn fẹ ya lọwọ Banki Agbaye, World Bank.

Awọn banki yoku ti yoo tun gbe owoya naa kalẹ ni French Development Agency (AFD), China-Exim Bank, International Fund for Agricultural Development (IFAD), Credit Suisse Group ati Standard Chartered/China Export and Credit (SINOSURE).”

”Lara awọn nkan ti wọn fẹ fi owoya naa ṣe ni atunṣe awọn ọpa epo to le ni marundinlogun ti yoo ṣe anfaani fun awọn ipinlẹ kaakiri Naijiria.”

”Owo ti a fẹ ya lọwọ banki agbaye naa yoo mu idagbasoke ba eto ẹkọ ni Naijiria, paapaa fun awọn ti ko ni owo lati lọ si ileẹkọ ni awọn agbegbe bii Katsina, Oyo ati Kano.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Nigba ti ipinlẹ bii Kogi, Kaduna, Kano, Cross River, Enugu ati ipinlẹ Eko pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ ijọba to n risi eto ọgbin yoo pese ọna igbalode ti awọn agbẹ le fi ṣe iṣẹ wọn.”

”Bakan naa ni ẹyawo lati banki agbaye naa yoo pese omi mimu to da gaara ni awọn agbegbe igberiko ni awọn ipìnlẹ bii Delta, Ekiti, Gombe, Kaduna, Katsina, Imo ati ipinlẹ Plateau fun ọdun marun un.”

”Bakan naa ni igbogun ti arun Coronavirus ko gbẹyin ninu ohun ti wọn fẹ fi ẹyawo naa gbogun ti, to fi mọ gbigbogun ti oju ọjọ to n ba awọn nkan ọgbin jẹ.

Awọn ipinlẹ mọkandinlọgbọn ti isẹlẹ yii si kan ni Akwa Ibom, Borno, Oyo, Sokoto, Kano, Katsina, Edo, Plateau, Abia, Nasarawa, Delta, Niger, Gombe ati Imo.

Awọn yoku ni Enugu, Kogi, Anambra, Niger, Ebonyi, Cross River, Ondo, Kaduna, Kebbi, Jigawa, Bauchi, Ekiti, Ogun, Benue, Yobe ati Kwara.”

Ijọba aarẹ Buhari ni oun yoo ṣe awọn oju ọna to ti bajẹ, to fi mọ oju irin ati ipese ina ọba to gbooro kaakiri orilẹede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ