Wọ́n fipá bá mi lòpọ̀ tán, díẹ̀ ló kù – Nkechi Blessing

Nkechi Blessing Sunday

Oríṣun àwòrán, nkechiblessingsunday/Instagram

Yoruba ni bi ọrọ ba se n pẹ nilẹ, gbigbọn ni yoo maa gbọn si.

Bẹẹ ni ọrọ ri nipa isẹlẹ to waye si Baba Ijesha, ẹni ti wọn fi ẹsun sise asemase pẹlu ọmọkan kan, to si n jẹjọ lọwọ.

Lọtẹ yii, ọkan lara awọn osere tiata lobinrin, ti ọrọ naa ka lara pupọ, Nkechi Blessing Sunday tun ti sọrọ lẹẹkan si nipa isẹlẹ naa.

Nkechi, lasiko to n kopa lori ifọrọwanilẹnuwo kan lori Instagram pẹlu Jude Jideonwo salaye idi ti ọrọ naa se ka lara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọkunrin kan fẹ fipa ba mi lopọ amọ diẹ lo ku:

Ninu alaye rẹ, Osere tiata lobinrin naa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni oun wa nigba ti ọkunrin kan fẹ fi tipa ba oun lopọ.

O salaye siwaju pe oun finu wenu nigba naa ni, amọ Ọlọrun nikan ni ko jẹ ki oun jẹ iwọ.

“Mo sọ fun ẹgbọn mi obinrin kan pe n ko ti mọ ọkunrin ati pe ko si akọ kankan to tii si mo ni asọ wo ri amọ o ni irọ ni mo n pa.

Nigba naa, ọti bia ni iya mi maa n ta, ti mo si maa n jo gan.

Lọjọ kan ni anti mi yii wa ni ka jọ lọ sile ọrẹkunrin rẹ, ti mo si tẹle amọ n ko mọ pe o tan mi lọ sibẹ ni lati fidi ootọ mulẹ boya lootọ ni n ko mọ ọkunrin.

Ko pẹ ta de ibẹ ni wọn fun mi ni ọti ẹlẹrindodo, ti mo si mu, ti anti mi si ni oun fẹ sare de ibi kan, to si ku emi ati ọrẹkunrin rẹ ninu ile.”

Nkechi tẹsiwaju pe bi anti oun se jade ni ọkunrin naa n gbe sunmọ oun, to si wa joko si ẹgbẹ oun pẹki-pẹki.

O ni ni kete ni skan oun lọ sibi ọrọ ajọsọ oun ati anti naa nipa pe oun ko mọ skunrin, ti ara si bẹrẹ si fu oun nitori oun ti ni oye nipa ibalopọ nigba naa.

O fikun pe ẹrun bẹrẹ si ni ba oun, ti oun si dide pe oun n lọ amọ ti ọkunrin naa dide lati di oun lọwọ mu, to si ni oun ko le lọ amọ ti oun yari mọ lọwọ.

Nkechi ni igba yii ni oun wa beere lọwọ ọkunrin naa pe se o fẹ fi tipa ba oun ni ajọsepọ ni? Eyi si lo ni o ya lẹnu pupọ, ti oun si ri ọna sa jade nibẹ.

“O yẹ ki wọn se idajọ iku fun awọn afipabanilopọ ni, ko si yẹ ki wọn maa gbe wọn lọ sile ẹjọ, ni kete ti ọkunrin kan ba ti fipa ba obinrin kan lopọ, ni ki wọn lu pa.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gbogbo awọn ọga tiata Yoruba lo n gba ibalopọ saaju fifun obinrin ni ere se:

Ninu ifọrọwerọ naa ni Nkechi tun ti si agbada lori ọrọ kan to ni se pẹlu ipa ti ẹgbẹ osere TAMPAN ko lasiko ti isẹlẹ Baba Ijesha waye.

Nkechi ni lootọ ni oun bu ẹnu atẹ lu awọn asaaju ẹgbẹ osere naa, ti Alagba Bolaji Amusan, ti ọpọ eeyan mọ si Mr Latin ko sodi nitori pe wọn ko tete sọrọ lori isẹlẹ naa.

Amọ o ni nigba to ya ni Latin se fidio kan pe awọn ko le le Baba Ijesha kuro ninu ẹgbẹ TAMPAN nitori kii se ọmọ ẹgbẹ awọn, ti awọn si fara mọ ohun to sọ.

“Amọ tẹ ba fẹ mọ idi ti ọpọ wọn se dakẹ jẹ nigba ti ọrọ Baba Ijesha sẹlẹ, idi ni pe iru kan naa ni wọn.

Ko fẹ ẹ si ọga elere kankan ninu ẹgbẹ TAMPAN to le sare jade sọrọ lori ẹsun ifipabanilopọ nitori ọpọ wọn ni wọn maa n kọkọ beere lati tu obinrin ni asọ wo, saaju ki wọn to fun ni ipa kan lati ko ninu ere.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bi wọn ba si fi sare sọrọ pẹrẹ, gbogbo awọn eeyan ti wọn ti fi ere gba asọ lara wọn ni yoo jade lati wa fi ẹsun kan awọn naa.

Lana kan abi omiran, gbogbo wọn ni wọn jẹbi ẹsun iwa ti Baba Ijesha hu, ti ẹnu wọn ko si le to ọrọ.

Wọn yoo fi ọwọ gbaya pe ti osere binrin kan ko ba sun pẹlu awọn, awọn ko ni gbe ipo kan fun ninu ere ti wsn ba fẹ se.

Nkechi Blessing wa ni isẹlẹ to ti waye saaju si oun lo mu ki oun gba ọrọ ẹsun Baba Ijesha naa kanri.