Wó ohùn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ nípa owó Naira tuntun

Owo Naira

Oríṣun àwòrán, Twitter

Lẹyin ti Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ṣe afihan owo tuntun ₦200, ₦500 ati ₦1000 lanaa, awọn eeyan ti n sọ orisirisi ọrọ lati fi ṣe ifẹhonuhan lori igbesẹ ọhun.

Ọpọ eeyan lo ti bọ si ori ayelujara lati bu ẹnu atẹ lu iru awọ ti owo tuntun naa gbeja, ti wọn si ni ko yato si owo ti tẹlẹ.

Lọjọru ọsẹ yii ni Aarẹ Buhari ṣe afihan awọn owo tuntun ọhun niluu Abuja lẹyin ọdun mọkandinlogun sẹyin ti ijọba ti ṣe atunṣe si owo gbẹyin.

Nigba to sọrọ lana, Aarẹ Buhari ni awọn owo tuntun ọhun ṣe anfani si ọrọ ajẹ, ti yoo si dẹkun iwa mago mago lorilẹede Naijria.

Owo tuntun ati owo Naira atijọ

Oríṣun àwòrán, Bayo Omoboriowo/Getty Images

Wo diẹ lara awọn nnkan ti awọn eeyan sọ lori ayelujara

Gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Basket Mouth wa lara awọn to kọkọ bu ẹnu atẹ lu ọna ti owo naa ba jade. O ni ṣe ni Banki apapọ kan pa owo ti tẹlẹ laro, ti wọn si gbe e sita fun lilo.

Aṣofin tẹlẹ lorilẹede Naijiria lati ipinlẹ Kano, Shehu Sanni naa bu ẹnu atẹ lu owo ọhun, eyi to ni o ba ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lọkan jẹ.

Olorin takasufe, Timi Dakolo naa pẹlu awọn to kọminu si igbesẹ owo tunutun ọhun, ti oun ni fi ẹsun ijọba apapọ ati banki apapọ orilẹede Naijiria pe wọn kan pa owo ti tẹlẹ laaro ni

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twiiter

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twittwr

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Aworan

Oríṣun àwòrán, Twitter

Wo àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàrin owó Naira tuntun tí Buhari fi lọ́lẹ̀ àti ti àtijọ́

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe ifilọlẹ awọn owo tuntun, ₦200, ₦500 ati ₦1000.

Nibi eto kan to waye ni ile ijọba niluu Abuja ni Ọjọru ni Buhari ti sẹ eyi.

Oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 ni Gomina Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele, kede pe awọn yoo tẹ owo tuntun jade.

Godwin Emefiele sọ nibi eto ifilọlẹ naa pe lati asiko yii lọ, banki yoo ma a tọ pinpin bi awọn eeyan ṣe n gba owo jade ninu asunwọn wọn.

“Adinku yoo ba iye ti awọn eeyan le gba jade ni banki, ẹni ti yoo ba si gba owo to pọ yoo tẹle awọn ilana kan ti yoo mu ki o rọrun lati tọpinpin nkan to fẹ ẹ lo owo naa fun.”

Bakan naa ni gomina CBN tun sọ pe ilana yii yoo mu ki Naijriia bọ si ọrọ aje ti ko nilo kiko owo kiri.

Owo atijọ naa ko nii ṣe itẹwọgba mọ lati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2023.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kejila, ọdun 2022 si ni awọn owo tuntun naa yoo jade sita fun araalu lati ma a ná.

Owo N1000 tuntun
Iwaju Owo N500 tuntun
Ẹ̀yìn Owo N500 tuntun
Owo N200 tuntun
Ẹ̀yìn owo N200 tuntun

Idi ti CBN fi ṣe owo tuntun jade

Gomina banki naa, Godwin Emefiele sọ pe awọn iṣoro ti awọn n koju ninu amojuto awọn owo naa to wa nita tẹlẹ lo fa igbesẹ naa.

Eyi si wa ni ibamu pẹlu abala keji ofin CBN ti ọdun 2007.

Emifiele ṣalaye pe lara awọn ipenija ti wọn n ni, ni bi awọn araalu kan ṣe n ko owo Naira pamọ.

O ni ida ọgọrin ninu ọgọrun owo Naira to wa lode, ni ko si ninu asunwọn awọn banki.

Ipenija miran ti Emifiele tun sọ pe o n koju CBN ni pe awọn owo to wa lọwọlọwọ ti dti ju nkan to yẹ fun níná lọ.

“Iru awọn nkan bayii n ta ẹrọ̀fọ̀ si aṣọ aala banki yii, to si tun ṣe akoba fun eto iṣuna.”

“Bakan naa ni awọn owo to wa nita lọwọlọwọ mu ki o rọrun fun awọn eeyan kan lati ma a ṣe ayederu owo, paapaa ₦500 and ₦1000.

Ọgbẹni emefiele sọ pe ilana awujọ agbaye to bojumu ni pe ki owo tuntun ma a jade ni ọdun marun si ọdun mẹjọ, amọ CBN ko tii tẹ owo tuntun jade lati bi ogun ọdun.

Àwọn tó kó owó jọ lọ́nà èrú ni yóò ní ìṣòro pẹ̀lú Naira tuntun – Buhari

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe oun faramọ erongba Banki Agba Naijiria, CBN, lati tun àwọn owo Naijiria tẹ̀.

Ninu atẹjade kan to fi sita ni oju opo ayelujara Twitter ileeṣẹ aarẹ lọjọ Aiku, ni Buhari ti sọ eyi.

Buhari sọ pe awọn owo tuntun naa yoo ko ìdààmú ba awọn to ko owo pamọ.

“Àwọn ọmọ Naijiria to ni owo lọ́nà aitọ, ti wọn ko pamọ sinu ilẹ yoo ni ìṣòro pẹlu awọn owo Naira tuntun.”

Ṣugbọn ṣa, o ni anfaani to pọ̀ ni awọn ọmọ Naijiria yoo jẹ nigba ti wọn ba ṣe ifilọlẹ awọn owo tuntun.

Buhari ni awọn oṣiṣẹ ati awọn oniṣowo to n pa owo lọ́nà to yẹ nikan ni ko le ni ìṣòro pẹlu owo tuntun.

Buhari ati minisita eto isuna tako ara wọn lori Naira tuntun

Sugbọn ṣa, ọrọ ti Buhari sọ yii tako nkan ti minista fun eto iṣuna Naijiria, Zainab Ahmed, sọ lori igbesẹ CBN.

Arabinrin Ahmed ti kọkọ sọ pe oun ko mọ nipa atunṣe owo Naira, to si ni ileeṣẹ eto iṣuna ko fọwọ́ si.

Lati igba ti Godwin Emefiele ti kede awọn owo tuntun naa, ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n fi erongba wọn han.

Bi àwọn kan ṣe sọ pe kii ṣe nkan ti ọ̀rọ̀ Naijiria kàn lasiko yii, ni awọn miran ń sọ pe igbeṣẹ naa yoo ba nkan jẹ fun awọn oloselu to ko owo pamọ.

Gomina banki apapọ lorilẹede Naijiria, Godwin Emefiele ti kede pe Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe ifilọlẹ awọn owo tuntun, N1,000, N500 ati N200 lonii.

Emefiele ṣe ikede yii nibi ipade awọn igbimọ baanki lorilẹede Naijria to maa n waye loṣooṣu niluu Abuja.

Gẹgẹ bii o ṣe sọ, o ni banki apapọ yoo ṣe afikun si ọjọ ti wọn fun eeyan lati ko awọn owo tẹlẹ waa si banki lati gba tuntun.

Emefiele lo kede lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwaa pe awọn yoo gbe awọn owo tuntun jade, ti yoo si wa si imusẹ lọjọ kẹẹdogun oṣu kejila ọdun yii ṣugbọn asiko maa wa ti awọn owo tẹlẹ ọhun ko le ṣe igba mọ, eyi ti wọn ni titi ọjọ kọkandinlọgbọn ni awọn fun wọn da.

Sugbọn o kede lana ọjọ Isẹgun pe banki apapọ ko ni le duro di ọjọ kẹẹdogun oṣu kejila mọ nitori pe Aarẹ ti ṣetan lati ṣe ifilọlẹ awọn owo naa lonii.

“Ọgọrun ọjọ ti to fun ẹnikẹni lati origun mẹrin orilẹede yii lati lọ kowo rẹ ti tẹlẹ lọ si banki, ko si gba owo rẹ pada ti a ba gbe owo tuntun jade.

“Lagbara Ọlọrun, lọla, to jẹ ọjọ kẹtalelogun oṣu kọkanla ọdun 2022, Aarẹ yoo ṣe ifilọlẹ awọn owo tuntun niluu Abuja ni dede ago mẹwaa.”