Ohun táa mọ̀ lórí rògbòdìyàn tó wáyé ní ààfin Ikirun rèé

Ọba ikirun

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Kọmíṣọ́nà fọ́rọ̀ oyè ní ìpínlẹ̀ Osun, Ọmọọba Adebayo Adeleke ti ṣàlàyé pé rògbòdìyàn tó wáyé ní ìlú Ikirun, ìpínlẹ̀ Osun ní ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kọkànlá, ọdún 2022 kò lọ́wọ́ ìjọba nínú rárá.

Ọmọọba Adeleke ní àwọn jàǹdùkú ló mọ̀-ọ́n-mọ̀ lọ kojú àwọn àwọn agbófinró lásìkò tí wọ́n ń gbìyànjú láti ṣe iṣẹ́ wọn láti dá ààbò bo àwọn tí wọ́n fẹ́ tún ààfin Akìrun ṣe ni.

Kọmíṣọ́nà náà ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jàǹdùkú tó lọ dáná sun ààfin náà ń fẹ̀hónú hàn ni lórí pé wọn kò fara mọ́ ẹni tí oyè Ọba ìlú náà já mọ́ lọ́wọ́, wọn kò gba ìlànà tó tọ́ láti fi ẹ̀hónú wọn hàn.

Ó ní tó bá jẹ́ wí pé ẹni tí ìjọba fọwọ́ sí láti di Ọba ìlú náà kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn, ó ní àwọn ìlànà tí òfin ti là kalẹ̀ láti lè pe ònítọ̀hún tàbí ìjọba lẹ́jọ́.

Ó fi kún un pé òfin fi àyè sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tó bá ní ìfẹ̀hónúhàn láti gba ilé ẹjọ́ lọ.

Ìjọba kọ́ ló máa ń yan Ọba, orúkọ tí àwọn afọbajẹ bá fi ránṣẹ́ sí ìjọba ni ìjọba máa tẹ̀lé

Nígbà tó ń ṣàlàyé àwọn ìlànà tí wọ́n tẹ̀lé láti yan ọba Ikirun, ó ní àwọn afọbajẹ ló fi orúkọ àwọn ọmọ oyè tó ra fọ́ọ̀mù láti dupò oyè Akirun ṣọwọ́ sí ilé iṣẹ́ àwọn lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ.

Adeleke ní lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò gbogbo àwọn tó forúkọ sílẹ̀ láti jẹ Ọba náàni àwọn ri wí pé ẹni tí yan yàn sípò ló pegede ní nú àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fún wọn.

“Tí ènìyàn méjì tàbí ènìyàn mẹ́ta bá ń du oyè kan, ẹnìkan náà ló máa padà já sí lọ́wọ́, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣẹlẹ̀ ní Ikirun”

Bákan náà ló pàrọwà sí àwọn tí wọ́n du oyè ṣùgbọ́n tó jẹ́ wí pé àwọn kọ́ ni oyè náà jámọ́ lọ́wọ́ láti ṣe sùúrù kí wọ́n fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹni tó wà níbẹ̀ kí ìlú lè tẹ̀síwájú.

Ó fi kun pé kò yẹ kí àwọn kan kó ara wọn jọ láti máa da ìlú rú nígbà tí kì í ṣe ẹni tí wọ́n fẹ́ ni ipò náà padà jọ́ mọ́ lọ́wọ́.

Kò yẹ kó jẹ́ àwọn ọmọ ọba ni yóò máa ṣaájú àwọn jàǹdùkú láti da ìlú rú – Elemo ìlú Ikirun

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Elemo ìlú Ikirun, Olóyè Bamidele Onifade ní ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́rú nígbà tí àwọn jàǹdùkú wá kojú àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti àwọn ọlọ́pàá lásìkò tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ ní ààfin.

Olóyè Onifade ṣàlàyé pé àwọn jàǹdùkú náà ló kó ìbọn àti àwọn nǹkan ìjà olóró láti wá kojú àwọn ọlọ́pàá náà.

Ó ní ó ṣeni láàánú wí pé ọmọ oyè kan, Lukman Olatunji pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí rògbòdìyàn náà wáyé àti pé àwọn agbófinró àti àwọn jàǹdùkú ni ìkojúìjà síra ẹni ti wáyé.

Bákan náà ló ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu wí pé àwọn ọmọ ọba àti ìdílé oyè ló ṣaájú ìwà jàǹdùkú láti da ìlú rú.

Ó ní ó dun òun wí pé àwọn kan le ṣi ọmọ náà lọ́kàn láti lọ gbé ìbọn láti kojú ìjà sí àwọn ọlọ́pàá tó sì ṣe àwọn ọlọ́pàá bí i mẹ́ta léṣe kí ìbọn tó ba òun náà.

Olóyè Onifade rọ gbogbo àwọn ará ìlú láti gba àláfíà ní ààyè kí ìdàgbàsókè àti ìlósíwájú tó lóòrìn le dé bá ìlú Ikirun.

Ṣé òòtọ́ ní pé Ọlọ́pàá ṣekúpa èèyàn kan ni ààfin Ọba Ikirun?

Aworan

Niluu ikirun, nipinlẹ Osun lana, wahala Ọlọbade gba ọna miran yọ lẹyin ti awọn janduku kan ṣe ikọlu si aafin Akinrun ti ilu Ikirun, ti wọn si dana sun un.

Ọpọlọpọ awuyeawuye lo ti tẹyin ikọlu naa jade, ti awọn eeyan si fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn ṣekupa ọmọba kan, ti orukọ rẹ n jẹ Lukman Olatunji.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe bii osẹ diẹ sẹyin ti awọn eeyan ilu ọhun ṣe ifẹhonuhan lori bi wọn ṣe yan ọba tuntun, wọn gbe adagagodo si ẹnu ọna aafin, eyi ti ko fun Ọba tuntun ni anfani lati wọle si aafin.

Bakan naa ni iroyin ọhun ni awuyewuye miiran bẹ silẹ lana lẹyin ti Ọba ati awọn ọlọpaa fẹ wọle si aafin, ti wọn si ṣina bolẹ lati ṣeruba awọn olufẹhonuhan ṣugbọn ti ibọn ba Olatunji, to si jade laye.

O to eeyan mẹrin miiran to farapa yanayana nigba ti awọn ọlọpaa fẹ gba akoso Aafin naa.

Igbesẹ awọn ọlọpaa yii ni o bi awọn ọdọ ilu ninu, ti wọn si dana sun Aafin Ọba lana, eyi to tun da kun rogbodiyan naa.

Oṣojumikoro, Gboyega Adebayo, nigba to ba ikọ oniroyin Punch sọrọ salaye pe oun fẹ lọ ran nnkan ni oun ṣalabapade awọn ọlọpaa ti wọn lọ si aafin, ti ọkan lara wọn yin si lọ ṣekupa ọmọba Olatunji.

“Ọta ibọn awọn ọlọpaa lo ṣekupa Olatunji, to si gbẹmi mi lẹsẹkẹsẹ.

“Awọn ọlọpaa lọ pe jorinjorin pe ko wa si ilẹkun aafin ọhun. Wọn bẹrẹ si maa yinbọn bolẹ lati sẹruba awọn eeyan, eyi ti ibọn ọhun ti wọn yin ṣe eeyan mẹrin miiran leṣe.

Ẹgbọn Olatunji, Tajudeen Gboleru ba ikọ oniroyin Punch sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ, o ni nigba ti awọn ọlọpaa gbinyanju lati wọ aafin ni wọn yin ibọn fun aburo.

“Eeyan kan lo wa si aafin pẹlu awọn ọlọpaa ati awọn ọmọ ologun, ibọn lara ọkan lara si lọ ba aburo mi”.

Ẹwẹ, nigba ti akọroyin BBC Yoruba, Olasunkanmi Ogunmoko yoo fi de ibẹ, awọn ọlọpaa tun ti gbakoso gbogbo agbegbe naa ti wọn ko si jẹ ki awọn oniroyin sunmọ ibẹ.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Yemisi Opalola ninu atẹjade to fi ransẹ si awọn akọroyin ni ileeṣẹ ọlọpaa ko le ṣekupa ẹnikẹni ati pe awọn lọ sibẹ lati lọ daabo bo awọn to ṣe atunṣe si aafin naa ni.

“Kọmiṣana ileeṣẹ ọlọpaa fẹ pe akiyesi awọn si iroyin ofege kan pe awọn ọlọpaa ṣina bolẹ fun eeyan niluu ikirun.

“Otitọ ibẹ ni pe nigba ti awọn ọlọpaa kan lọ daabo bo awọn to n ṣe atunṣe si aafin Akinrun, awọn afurasi agbebọn janduku ṣina bolẹ fun awọn ọlọpaa, ti ibọn si ba meji laarin wọn, Obajobi ati Raji Abiodun.

“Ti wọn si gbe wọn digbadigba lọ si ile iwosan fun itọju. Awọn janduku yii wa gbera lati lọ dana sun aafin, ti wọn si tun kọlu awọn osisẹ panapana meji, Orunwumi Roseline ati Abel Olayinka .

Opalola ni Kọmiṣana ti wa rọ awọn obi ati alagbatọ lati kilọ fun awọn ọmọ wọn ki wọn dẹkun iwa ibajẹ ati jadijagan. O ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ko ni muu ni kekere fun ẹnikẹni ti iwadii ba fihan pe o lọwọ ninu ikọlu naa.