Wo iye èèyàn Ukraine àti àjòjì tó ti kú láti ìgbà tí Russia ti gbógun ti Ukriane

Russia war

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orilẹ-ede Ukraine ti sọ pe ko din ni ẹgbẹrun meji araalu to ti ku bayii lẹyin ti orilẹ-ede Russia kogun lọ ba awọn.

Yatọ si ẹgbẹrun meji eeyan yii, awọn oṣiṣẹ pajawiri mẹwaa lo tun ti ba ogun naa lọ.

Awọn adoola ẹmi ti pa ina irinwo to ṣẹyọ latari awọn ado oloro ti Russia fi n ranṣẹ si Ukraine.

Aṣoju ijọba Ukraine ni “Laarin ọjọ meje ti ogun yii bẹrẹ, Russia ti ba aimoye ibudokọ jẹ, iyẹn yatọ ọkẹ aimoye ilegbe, ile iwosan atawọn ile ẹkọ awọn ọmọ wẹwẹ.”

Nnkan bii ọsẹ kan sẹyin ni Russia bẹrẹ ikọlu si Ukraine.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn ọmọ ile ẹkọ dero atimọle nitori wọn ṣe ifẹhonuhan lodi si Russia

Awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ kan ni Russia ti dero agọ ọlọpaa niluu Mosco latari pe wọn ṣe iwọde lodi si bi orilẹ-ede wọn ṣe gbe ogun ti Ukraine.

Awọn akẹkọọ naa ṣe iwọde ọhun nipa fifi awọn awọn ododdo si ẹnu ọna abawọle ọọfisi ijọba Ukraine ni Moscow, to ti wọn si tun gbe patako lọwọ pẹlu akọle “A ko fẹ ogun.”

Russian primary school children detained for anti-war protest

Oríṣun àwòrán, @novaya_gazeta

Ẹwẹ, ileeṣẹ iroyin Novaya Gexeta ti jabọ pe awọn ọmọde naa ti gba itusilẹ bayii.

Ṣaaju ni aworan kan ti kọkọ lu sita, eyii to ṣafihan awọn ọmọde naa ni ahamọ, eyii ti ọpọ gbagbọ pe o ṣeeṣe ki wọn ya ninu ọkọ “Black Maria” ọlọpaa.

Russian primary school children detained for anti-war protest

Oríṣun àwòrán, @novaya_gazeta

Aworan mii tun ṣẹyọ, nibi ti awọn ọmọde naa ti gbe akọle lọwọ ninu ọọfisi ọlọpaa.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ọdun 2022, ni Russia bẹrẹ ogun lẹyin ti ede aiyede ti n waye laarin orilẹ-ede mejeji lati ọdun 2014.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ