A ó fòfin dé ‘Loan App’ tó bá ń dún kookò mọ́ àwọn onîbàárà wọn- FCCPC

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Yiya owo lori ayelujara ni ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria gunle, ti wọn si ma n fi tan iṣoro owo to jẹ kiakia.

Sugbọn ti wọn ba kuna lati san owo yii, awọn ileeṣẹ to ya wọn lowo ma dunkoko mọ wọn, ti wọn si ma fi atẹjisẹ kogbakogba ranṣẹ si gbogbo eeyan to wa ni ori ẹrọ ibaraẹnisọrọ wọn pẹlu aworan pe wọn jẹ gbese.

Idunkoko ni o ti fa ọpọlọpọ wahala ni Naijiria, ti awọn mii si ti padanu iṣẹ wọn nitori idunkoko yii ni ọna kan tabi mii.

Sugbọn Ọga fun ileeṣẹ ijọba, Federal Competitiona & Consumer Protection Commission, FCCPC ni idunkoko yoo di ohun igbagbe laipẹ.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC, nibi to itan imọlẹ si oro naa ati awọn ọrọ mii, to si tun salaye igbesẹ ijọba.

Aṣoju alaga Ajọ naa, Adamu Abdullahi ni idunkoko yii ko ni waye mọ nitori ijọba ti n gbe igbesẹ lori ọrọ.

“A o ni faye gba eyi mọ nitori awọn onibara ni wọn n dunkoko mọ, koda eyi ki n ṣe ija wa nikan, EFCC, CBN,NITDA ati awọn ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ti da igbimọ silẹ.

“Gẹgẹ bii a ṣe ri pe ori ayelujara ni wọn ti n siṣẹ, awọn ileeṣẹ yii ko ni ọfisi idanimọ, ti a ko si mọ ẹnikẹni mọ wọn, a o lọ ba Google ati Apple store pe a fẹ ki wọn wọgile awọn ileeṣẹ yii.

“A o tun kesi ajọ CBN pe li wọn wọgile awọn akanti ti wọn fi n siṣẹ.”

Abdullahi tẹsiwaju pe lẹyin ti awọn ba ti awọn akanti, awọn olori ileeṣẹ naa yoo fi ẹsẹ wọn rin wa ba awọn, ti awọn si ri pe wọn tọwọ bọ iwe, ti wọn yoo mọ ofin to wa ninu owo yiya lorilẹede Naijiria.

O ni ajọ sẹtan lati le fi iya to yẹ jẹ Loan App ti onibaara wọn ba fi ẹjọ wọn sun pe wọn dunkoko mọ oun.

O ni bayii ikilọ ni awọn n fun awọn ileeṣẹ ‘Loan App’, to si jẹ ọjọ Aje ni awọn bẹrẹ igbesẹ yii.

“Wọn ti gba pẹlu wa pe awọn ko ni ma tọwọ bọ foonu awọn onibara wọn, ti wọn si ni ma fi fọnran wọn ranṣẹ kiri, ti a ba gbọ. A o fofin de wọn ni ẹsẹkẹsẹ.”

Ofin tuntun ti wa fun awọn ontaja ayelujara- FCCPC

Awọn eeyan to n taja lori ayelujara ni lati tẹti, ki wọn ran oju wọn daada.

Abudullahi ni awọn ti bẹrẹ si ni ṣe iwadi awọn onkowo kan ti wọn fọrukọ silẹ lorilẹede Naijiria, ti wọn si n taja lorilẹede Naijiria sugbọn owo ilẹ okere ni wọn n fi ta ọja wọn.

O ṣalaye pe ilana wa fun awọn to n taja lori ayelujara eyi ti o jade sita ni oṣu mẹta.

“Naira ni ojulowo owo fun karakata ọja lorilẹede Naijiria.”

Abdullahi ni igbeṣẹ FCCPC lati ti ileeṣẹ ontaja Chinese niluu Abuja, ti iroyin nipa rẹ lu gbogbo ayelujara laipẹ yii ko sẹyin pe wọn wu wa tako ofin orilẹede Naijiria.

O ni yatọ si pe wọn ṣẹ si ofin, wọn tun n wa karakata wọn pẹlu owo ilẹ okere dipo owo naira.

Ti a ba kẹfin ayederu ọja kankan ninu ọja, a o palẹmọ rẹ

Ayederu ọja ati gbigbe owo le lori ọja jẹ iṣoro nla ti ọpọ tun n lakọja lorilẹede Naijiria.

Abdullahi ni ọpọ awọn Naijiria ni wọn n reti pe ki ijọba kede owo ti o yẹ ki awọn nnkan tita lati ẹka FCCPC sugbọn iyẹn ki ṣe iṣẹ wọn rara.

O ni FCCPC ko ni fi aye silẹ fun ayederu lati ma jẹ tita ninu ọja tabi nibikibi lorilẹede Naijiria.

“Ti a ba ri ayedere nnkan lọja, ofin ni a ni ẹtọ lati gbe.

“Apo baagi Stallion ati Caprice ti wọn ko ṣe mọ lati ọdun 2018 ni a ri ninu ọja, a dẹ gbe lọ si ọfisi wa, ki wọn ba wa lati ṣalaye ibi ti wọn ri ọja naa.”