Daniel Anjọrin ni orúkọ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tí wọ́n pa ní London – Ọlọ́pàá

Aworan Daniel Anjọrin ti wọn pa ni London

Oríṣun àwòrán, Metropolitan Police

Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe Daniel Anjọrin lorukọ ọmọ ọdun mẹrinla ti wọn fi ida oloju meji gun nibi ikọlu to waye ni Hainault, Ariwa-Ila-Oorun London lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.

Akẹkọọ ile-ẹkọ Bancroft ni wọn pe Daniel, gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe sọ ninu fọto rẹ ti wọn fi sita lọsan ana.

Ile-ẹkọ kan naa ni Daniel ati afurasi tọwọ tẹ, Grace O’Malley-Kumar jọ n lọ.

Awọn alakoso ile-ẹkọ Bancroft nigba ti wọn n kẹdun iku Daniel, wọn sọ pe “Iwa irẹlẹ ati iwa tutu rẹ yoo maa wa lọkan wa, eyi ti yoo jẹ ki a maa fi ranti ẹ titi lai”.

Bakan naa, The Met nigba ti wọn n gbe ẹkunrẹrẹ ohun to ṣẹlẹ sita ṣalaye pe afurasi ọhun kọlu ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan lasiko to fi bọọbi kọlu dukia to wa ni Laing Close.

Lẹyin eyi ni wọn lo tun kọlu ọkunrin kan to fi ọrun ṣeṣe. Ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji miran tun ni ọgbẹ ni apa ninu ile to wa nitosi.

Awọn oṣiṣẹ agbofinro meji lo fi ara pa yannayanna.

Afurasi ẹni ọdun mẹrindinlogoji naa ti wa lahamọ awọn ọlọpaa lẹyin ti wọn rọwọ to o, lẹyin to ti gba itọju lọsibitu nitori ipalara toun naa ni.

Awọn ẹbi ati ọrẹ ti ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn obi Daniel lati tu wọn ninu kuro ninu ibanujẹ.

Kí lẹ ti gbọ́ nípa ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tí wọ́n pa ni Hainault ni London?

Aworan ibi isele naa

Ko si ohun miran to tun n ja ranyin-ranyin lori ikanni ayelujara X lasiko yii to kọja ti ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹrinla ti wọn ṣeku pa ni Hainault.

Ko din ni igba ẹgbẹrun mọkandinlọgbọn ti wọn ti darukọ Hainault lori ikanni X latigba ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa ṣi n tẹsiwaju lori iwadii wọn.

Yatọ si eyi, Hainault tun wa lara awọn agbegbe ti awọn eeyan n wa julọ lori ikanni ayelujara ti Google lasiko yii.

https://www.bbc.com/yoruba/articles/cd185drgj2ro

Ohun ti a mọ nipa ikọlu Hainault

Bi ẹyin ba ṣẹṣẹ n darapọ mọ wa, eyi ni akojọpọ koko nipa ohun ṣẹlẹ gangan ni Hainault

Ki lo ṣẹlẹ?

Ọkunrin ajorinmọrin kan to n rọ ada oloju-meji ti a mọ ‘sword’ ni wọn lo ṣe ikọlu si awọn eeyan lagbegbe Hainault, to si tun ti ṣe ikọlu si awọn mẹrin miran.

Nibo lo ti ṣẹlẹ?:

Agbegbe kan ti wọn n pe ni Hainault ni, o si wa ni apa Ariwa-Ila-Oorun London.

Igba wo lo ṣẹlẹ?

Aarọ ana, ọjọ Iṣẹgun lo waye ni nnkan bi agogo meje owurọ

Awọn wo lo fara kaasa?

Ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹrinla kan lo ku lasiko ti ọkunrin ajorinmọrin naa gun-un. Awọn mẹrin miran naa tun farapa, leyi ti ọlọpaa meji naa wa lara wọn.

Ki lo tun wa ṣẹlẹ?

Awọn ọlọpaa le afurasi kan, wọn si gba wa ọna lati mu nipa fifi ohun ija onina mu.

Mọ̀ síi nipa afurasi náà?

Ta ni afurasi naa?

Ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji kan ni ọwọ tẹ nibi iṣẹlẹ ọhun.

Awọno ọlọpaa ko si tii fi ọrọ wa lẹnu wo nitori pe ile-iwosan lo wa nitori bo ṣe fi ara pa lasiko to wa ọkọ bọọsi lati fi kọlu ile kan, ṣaaju ikọlu ọhun.

Ohun ti a ko mọ?

Titi di asiko ti a pari akojọpọ yii ni a ko tii le sọ pato iru awọn ti wọn fi ara pa naa jẹ,

to fi mọ ọmọ ọdun mẹrinla to ku nibẹ.

Ọlọpaa funra wọn ko tii fi orukọ afurasi naa sita, bẹẹ si ni a ko mọ oru ẹni to jẹ ati idi to fi ṣe ikọlu ọhun.