Àwọn ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Ukraine yóò máa dé láti òní lọ- Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè

Geoffrey Onyeama

Oríṣun àwòrán, Punch

Ìjọba àpapọ̀ ti ní àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó há sí orílẹ̀ èdè Ukraine yóò máa wọ orílẹ̀ èdè yìí láti ọ̀la lọ bí àwọn ọkọ̀ òfurufú tí yóò máa gbé wọn ṣe ti ń gbéra láti òní.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ akọ̀wé àgbà ilé iṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè, Gabriel Aduda lórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter ní àwọn ti ní àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó ti sá sí àwọn orílẹ̀ èdè bíi Romania, Hungary, Poland àti Slovakia.

Aduda ní àwọn ọkọ̀ òfurufú Max Air tí yóò máa kó àwọn ènìyàn 560 kúrò ní Romania, Airpeace yóò lọ Poland lati kó àwọn ènìyàn 364 àti àwọn 360 ènìyàn ní Hungary.

Àtẹ̀jáde ọ̀hún fi kun pé ní ọ̀la ni ìrètí wà pé àwọn ènìyàn náà yóò balẹ̀ sí Nàìjíríà.

Bẹ́ẹ̀ náà ló tẹ̀síwájú pé àwọn yóò sa gbogbo ipá àwọn láti ri dájú pé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà padà sílé láyọ̀.

Àtẹ̀jáde ilé iṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àwọn ọmọ Nàìjíríà kò fẹ́ padà sílé:

Ẹ̀wẹ̀, Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Geoffrey Onyema ti ni àwọn ọmọ Nàìjíríà kan tó wà ní orílẹ̀ èdè Ukraine tí Russia ń gbógun kọlù kò fẹ́ kúrò ní orílẹ̀ èdè náà padà wálé.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Onyema sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń bá Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila ṣe ìpàdé.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ó ní lónìí ni àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ síní kò àwọn ènìyàn tó ṣetán láti padà sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan náà ló fi kun pé gbogbo jíjẹ àti ibùgbé àwọn tó ti sá kúrò ní Ukraine bọ́ sí àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn ni àwọn ń gbọ́ títí àwọn yóò fi kó wọn wálé.