Sola Sobowale ṣàlàyé bí ó ṣe rìn ìrìnàjo láti ayé ‘Toyin Tomato’ lọ ṣé ‘Caregiver’ ni London

Aworan Sola Sobowale

Oríṣun àwòrán, Instagram

Gbajugbaja oṣere tiata lorilẹede Naijiria, Sola Sobowale ti sọ ohun to lakọja lasiko to n sisẹ olutọju ’Caregiver’ niluu London ati idi to fi kuro lorilẹede Naijiria lasiko naa.

Ilumọka oṣere, ẹni ọdun mejidinlọgọta tan imọlẹ si awọn iṣẹlẹ yii lasiko to n ṣe ifọrọwerọ lori eto Teju Baby Face lọjọ Isẹgun.

Sobowale ni oun kuro lorilẹede Naijiria lọdun 2004, to si pada lẹyin ọdun mejila fun ayẹwo lati kopa ninu ere sinima kan.

Nigba ti wọn bi pe kilode to fi yi orukọ rẹ si ‘Elevated ọmọ ọdọ’, o ni tumọ si eeyan to ti la ọpọ nnkan kọja laye sugbọn o ni ore ọfẹ lati bori gbogbo wọn.

Sola sobowole tun salaye pe:

“Bẹẹni. O waye lẹyin Toyin Tomato- ere Super Story, ni mo gbera lọ si ilu London.

Mo kuro lorilẹede Naijiria patapata ni ọdun 2004, ti n ko si wale rara titi to fi di igba ti mo wa ṣe ayẹwo lati kopa ninu ere Wedding Party lọdun 2016.”

Lẹyin to ti kopa ninu ọpọ sinima paapa Toyin Tomato ni ọdun 2000, Sola Sobowale yẹra diẹ kuro nidi iṣẹ sinima, to si pinnu lati lọ ṣe iṣẹ miiran niluu London.

“Nigba ti mo bẹrẹ si ni ma siṣẹ ni ọfisi naa, a ni awọn eeyan lati Naijiria, Jamaica, Ghana, ti gbogbo wọn si mọ Sola Sobowale. Sugbọn ohun to ru wọn loju ni orukọ mi to jẹ Olu, ti ki si n ṣe Olusola.”

O tẹsiwaju pe igba kan ti ariwo gbode pe oun ti jade laye.

“Mo gbagbọ pe ki eeyan ṣe iṣẹ ni ọna to tọ. Ko si iṣẹ ti n ko le ṣe lati fi ounjẹ sori tabili mi, lati pese fun awọn ọmọ mi, yatọ si iṣẹ aṣẹwo ati lilu eeyan ni jibiti.”

Ṣe loootọ nipe awọn ọlọpaa mu Sola Sobowale fun gbigbe ogun oloro ni Saudi Arabia?

Aworan Sola Sobowale

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu alaye rẹ, Sola Sobowale tan imọlẹ si iroyin kan to gbode pe wọn mu fun ẹsun pe o gbe ogun oloro lorilẹede Saudi Arabia.

O ni pe nigba ti oun kuro lorilẹede Naijiria lọ si ilẹ United Kingdom, ọpọlọpọ awọn kugbakugba ọrọ ni awọn eeyan n sọ nipa rẹ, paapa eyi ti wọn ni pe wọn ṣekupa ni Gulf nation.

“Ọlọrun da mi lọla nitori ọpọ nnkan ni wọn ti kọ nipa mi nigba ti mo kuro ni Naijiria, ọpọ awọn nnkan ti ko da,” Sobowale ṣalaye.

Ẹwẹ, o ni pupọ awọn nnkan wọnyi ni ko ba ninu jẹ rara, ni iwọnba pe o ni alaafia pẹlu Ọlọrun.

“Mo ranti, nigba ti mo n ṣe iṣẹ mi ni UK, awọn iwe iroyin lorilẹede Naijiria kọ nnkan nipa mi pe mo ti inu ogo di ẹni ilẹlẹ.”

O ni oun ranti igba ti ọpọ bu ẹnu atẹlu oun pẹlu iroyin pe o n ba ẹgbọn rẹ, Kike Oyelami ta ounjẹ ni ile ounjẹ kan niluu London.

Agba osere naa ni: Mo ma n lọ si ibẹ lasiko ti n ko ba si nibi iṣẹ. Mo ma n tẹ ẹba, gun iyan, ti mo si tun ma ba wọn gbe ounjẹ fun awọn onibaara.

“Wọn ri mi. Wọn dẹ gbe jade pe Sola Sobowale ti n ta ẹba.”

O ni ọkan gboogi irọ ti o jade nipa oun ni eyi ti wọn gbe jade pe wọn ṣekupa oun fun ẹsun gbigbe ogun oloro lorilẹede Saudi Arabia.

O ni oun to jọ ni loju ni pe oun gan ko mọ apa ibi ti Saudi Arabia wa ninu maapu.

“Wọn ni wọn pa mi ni Saudi Arabia pe mo gbe ogun oloro. Wọn ni awọn ọlọpaa mu mi, wọn dẹ tun ge ẹsẹ mi, ọwọ mi ati pe mo sọfun pe ilumọka ni mi Naijiria

“Nitori naa, wọn ni mo fi sọ pe ki wọn pa mi, wọn dẹ pa mi”

Sola Solabowale ni kete ti oun pada si orilẹede Naijiria ni oun wọgile iroyin naa ati pe oun ko de ilu Saudi Arabia ri laye oun.”