NÍ YÀJÓYÀJÓ Ọmọ ogun Russia bíi 500 ló ti bá ogun lọ ní Ukraine

Copyright: BBC

Aarẹ Mhammadu Buhari ti fọwọsi owo to to miliọnu mẹjọ
ati aabọ dọla lati fi ko awọn ọmọ Naijiria to ha si orilẹede Ukraine

Minisita keji fọrọ ilẹ okeere, Zubairu Dada, lo
kede bẹẹ pẹlu afikun pe igbimọ alasẹ ijọba lo fontẹ lu owo naa nibi ipade wọn
to waye lọjọ Aje eyi ti igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo dari.

Minisita naa ni ọkọ ofurufu Air Peace ati Max Air
nijọba yan lati pese ọkọ ofurufu mẹta lọ ko awọn ọmọ Najiria naa wale.

Ki lo sẹlẹ sẹyin:

Orilẹede Russia ati Ukraine ni wọn ti n doju ogun
kọ ara wọn lati bii ọsẹ kan sẹyin nitori ipinnu Ukraine lati dara pọ mọ ẹgbẹ NATO

O si to ẹgbẹrun marun ọmọ Naijiria to n kẹkọọ
lorilẹede naa ti ogun ọhun ti se akoba fun.

Awọn ileesẹ asoju ijọba Naijiria to wa ni Romania,
Hungary ati Poland si ti gbalejo awọn ọmọ Naijiria to to ọtalerugba o dinmarun, ti wọn sa kuro nilẹ Ukraine wa sawọn
orilẹede naa.

Minisita fọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama, si ti
kede saaju pe ijọba apapọ yoo bẹrẹ si ni ko awọn ọmọ Naijiria wale lati Ukraine,
bẹrẹ lati oni ọjọru.