Wo èsì ilé ìtura Zanzibar tí ọmọbìnrin yìí ní wọ́n fẹ́ fipá bá òun lòpọ̀ níbẹ̀

Zainab Oladehinde

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ajọ to n ṣe amojuto irinajo igbafẹ nilu Zanzibar lorilẹ-ede Tanzania, ti bẹrẹ iwadii si ẹsun ifipabanilopọ ti ọmọ Naijiria kan, Zainab Oladehinde, sọ pe o ṣẹlẹ̀ sii nile itura Warere, lasiko to lọ fun isinmi.

Gẹgẹ bi Zainab ṣe sọ, oṣù Kẹrin, ọdun 2021, lo de si ile itura Warere, lati gbadun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ọdun ikẹtalelogun.

Ninu awọn ọrọ to kọ si ori Twitter lọjọ Satide, Zainab sọ pe ni ọjọ gan-an naa ti oun de ile itura Warere Beach Hotel, ni ẹnikan gbiyanju lati fi ipa ba oun lopọ.

O ni “ko tii ju wakati diẹ ti mo sùn, mo dede ni imọlara pe ẹnikan n fi ọwọ kan ọyàn aya mi, bi mo ṣe sun ni ihoho”.

” Mo kọkọ ro pe àlá ni. Mo tun sun pada. Idi ni pe mo ti ilẹkun yaara ti mo wa ki n to sùn.

O ṣalaye pe lẹyin isẹju diẹ, ajeji ọkùnrin to wọle ti oun bẹ̀rẹ̀ si ni fi ọwọ oun pa nkan ọmọkùnrin rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Asiko naa lo to la oju rẹ kedere, láti ri pe lootọ ni oun wa ninu ewu.

Ko pẹ, ko jina, okùnrin naa gbiyanju lati sùn lee lori.

“Mo parọ fun ko lọ mu rọba idaabobo wa, nirori pe mo ni aarun HIV.

” Bo ṣe gbọ HIV, lo bẹ̀rẹ̀ si ni fun mi ni ọrùn. Mo tun tun ọrọ naa sọ.”

Bayii ni ọkùnrin naa ṣe jade, to si sọ pe oun n pada bọ.

Zainab lo anfaani naa lati sa jade ninu yara, to si salọ si yara tọkọtaya ọmọ orile-ede Russia kan ti wọn jọ di ọrẹ ni ọsan ọjọ naa.

O fi ọrọ naa to ẹni to ni ile itura naa létí, ko da o lọ si àgọ́ ọlọpaa, sugbọn wọn le e danu pe ẹnikẹni ko gbiyanju lati fi ipa ba a lopọ.

Zainab ṣalaye pe ede Swahili ti oun ko gbọ, ni gbogbo wọn (àwọn ọlọpaa, alamojuto ile ìtura, ati àwọn osisẹ) fi n sọrọ ni agọ ọlọpaa, bo tilẹ jẹ pe wọn gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì.

Yatọ si ọrọ ifipabanilopọ, Zainab sọ pe wọn tun ji owo rẹ to le ni ẹgbẹ̀rún kan Dọla to tọju sinu ẹrú rẹ, lasiko to fi yara naa silẹ.

Ile itura Warere Beach Hotel f’esi

Atẹjade ile itura Warere

Oríṣun àwòrán, Warere Beach

Lẹyin ti Arabinrin Zainab Oladehinde sọ nipa iriri rẹ, awọn alaṣẹ ile ìtura Warere Beach Hotel ti fesi.

Ninu ọrọ kan ti awọn naa kọ si ori Twitter, wọn ni lootọ ni ọmọbìnrin naa gba yara nile ìtura wọn.

Ile itura naa sọ pe ọrọ naa de etigbọ ileesẹ ọlọpaa ni agbegbe Nungwi, ni Zanzibar.

Wọn fi kun pe kọmisanna agbegbe naa, to fi mọ igbakeji aarẹ ijọba Zanzibar, gbọ nipa iṣẹlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Wọn ni sugbọn Zainab ko gbà lati jẹ ki wọn o tọ pinpin ẹ̀sùn naa.

Warere Beach Hotel sọ pe “àwọn ọlọpaa ní ọwọ Zainab ni ẹbi wa, kii ṣe nitori pe a ko ṣe amojuto to yẹ nile itura wa.

Koda, wọn ni afurasi ti Zainab tọ́ka si sọ pe fúnra ọmọbìnrin naa lo pe oun wọ yaara fun ibalopọ, sugbọn oun jade lọ wa kọndọọmu nitori HIV to sọ pe oun ni.

Àwọn eniyan sọ iriri wọn lori Twitter

Lẹyin ọrọ ti Zainab sọ nipa iriri rẹ, ọ̀pọ̀ eeyan, paapaa awọn obinrin, lo ti n sọ iriri wọn n’ilu naa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe iru nkan yii ṣẹlẹ̀ si wọn lasiko ti wọn rinrinajo igbafẹ lọ silu naa, ni awọn kan n sọ pe wọn ja àwọn lole.

Koda, kaakiri agbaye ni awọn eeyan ti n da si ọrọ naa lori Twitter bayii.

Atẹjade ori Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Atẹjade ori Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Atẹjade ori Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ìjọba Zanzibar dasi ọrọ Zainab

Esi ijọba Zanzibar

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ajọ to n samojuto igbafẹ ni Tanzania sọ pe oun ti n wadii ẹsun naa bayii.

Bakan naa ni wọn bu ẹnu ẹtẹ lu kikọlu awọn arinrinajo silu naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Nkan to yẹ kí o mọ nipa ilu Zanzibar

Agbegbe to wa laarin omi ni erekusu Zanzibar.

O da duro, to si ni aarẹ to n dari ijọba rẹ. Ṣùgbọ́n, lara orile-ede Tanzania ni wọn wa, ti wọn si n na owo kan naa.

Irinajo igbafẹ si ni ọrọ aje gboogi ti wọn ni, nitori pe lojoojumọ ni ogunlọgọ eeyan n gunlẹ sibẹ fun isinmi ati faaji.