Ìpadàbọ̀sípò àti ọrọ̀ yóò wà fún Nàìjíríà – Osinbajo gbàdúrà

Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gẹgẹ bi awọn ọmọlẹyin Kristi kaakiri agbaye ṣe n ṣe ajọdun ọdun ajinde, igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo ti fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ipadabọsipo, alafia ati ọjọ ọla to lọrọ lai boju wo gbogbo ipenija to wa nilẹ ni yoo jẹ ti Naijiria.

Ọjọgbọn Osinbajo fi eyi lede lọjọ Aiku ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn oniroyin ni kete ti isin ọdun Ajinde pari ni Ṣọọṣi to wa ni ile Aarẹ l’Abuja.

“Ọrọ mi, adura naa ni. Ajinde Jesu Kristi Oluwa wa jẹ akoko oni itumọ fun gbogbo awa Kristẹni. Ohun pataki to si yẹ ka fi sọkan ni ireti ajinde”,

Igbakeji aarẹ sọ eyi ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ iroyin, Laolu Akande fi sita.

“Nibikibi ti sisọ ireti nu ba wa, mo gbadura ireti naa yoo di gbigbe dide, nibi ti ibẹru ba wa, mo gbadura fun igboya. Nibi ti fifi ẹtọ du ni ba wa, mo gbadura fun ilọrọ ati ọpọ yanturu”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Igbakeji Aarẹ fi kun un pe o le da bii pe awọn nkankan ti ku ṣugbọn agbara ajinde jẹ ọkan to n fi aridaju han fun wa pe iye ṣi wa lẹyin iku.

O ni “nitori eyi a ni igboya kikun paapaa fun orilẹede wa to jẹ pe gbogbo ibi ni fifi ẹtọ dun eeyan wa, amọ ipadabosipo yoo wa eyi si ni ileri ajinde”.

Ọjọ Aiku lasiko ọdun Ajinde jẹ eyi ti gbogbo eeyan lagbaye maa n yẹ si lati ṣaami ajinde Jesu Kristi to jinde kuro ninu oku.

Iyawo igbakeji Aarẹ, Arabinrin Dolapo Osinbajo naa wa nibi isin naa pẹlu Sẹnetọ Bwacha ati Họnọrebu Danjuma Shiddi ti awọn mejeji wa lati ipinlẹ Taraba.

Bakan naa lawọn ọga ọga ni ọfiisi Aarẹ naa darapọ mọ isin ọhun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ