Ọlópàá 16 farapa nínú ikọlù tó wáyé torí àwọn kàn gbèrò láti dáná sún Quran

Aworan taya tawọn oluwọde sọ ina si ni Norrköping lọjọ Aiku

Oríṣun àwòrán, EPA

Ikọlu to n waye lawọn ọpọ ilu lorileede Sweden ti wọ ọjọ kẹrin bayi ti ko si ṣẹyin bawọn kan ṣe n dana sun iwe mimọ awọn musulumi al Quran.

Awọn ikọ alakatakiti kan ti wọn tako ki awọn eeyan orileede miran wọ ilẹ wọn lo wa nidi surutu yi.

Ileeṣẹ iroyin nilẹ naa sọ pe eeyan mẹta farapa ni ilu Norrköping lọjọ Aiku nigba ti awọn ọlọpaa yinbọn lu awọn onijagidijagan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Aimọye ọkọ ọlọpaa ni wọn dana sun ti ọlọpaa si mu o kere tan eeyan mẹtadinlogun.

Lọjọ Abamẹta,ọpọ ọkọ to fi mọ bọọsi kan ni wọn tun dana sun lasiko iwọde ni ilu Malmo to wa ni Guusu ilẹ naa.

Ṣaaju ni ijọba orileede Iran ati Iraq ti kesi awọn aṣoju Sweden nilẹ wọn lati fẹhonu wọn han lori didana sun Quran to n waye.

Ọkọ ti wọn dana sun ni agbegbe Rosengrad ni Malmo lọjọ Abamẹta

Oríṣun àwòrán, Sweden Out/TT News Agency via Reuters

Olori awọn ikọ alakatakiti Stram Kurs ti a tun mọ si Hard Line, arakunrin Rasmus Paludan, sọ pe oun ti dana sun Qurani ati pe oun yoo tun ṣe bẹ sii.

O kere tan ọlọpaa mẹrindinlogun lo farapa ti wọn si dana sun ọpọ ọkọ ọlọpaa ninu ikọlu to waye ni Ọjọbọ, ọjọ Ẹti ati Abamẹta.

Eyi ṣẹlẹ lawọn aaye ti awọn ikọ alakatakiti yi ti n gbero lati ṣe ayẹyẹ ni agbegbe Stockholm ati awọn ilu Linköping ati Norrköping.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Kini olori ikọ alakatakiti yi leri pe oun yoo ṣe?

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Deutshe Welle ṣe sọ,ohun ti Rasmus Paludan sọ pe oun yoo ṣe ni iwọde miran lọjọ Aiku ni ilu Norrköping.

Eleyi to mu kawọn to tako iwọde rẹ peju sibẹ lati ṣe atako rẹ.

Awọn ọlọpaa agbegbe naa sọ ninu atẹjade pe awọn yin ibọn sawọn oluwọde yi lati fi ṣe ikilọ lẹyin ti wọn doju ija kọ awọn.

Aworan ọkọ ọlọpaa ti wọn dana sun

Oríṣun àwòrán, EPA/SWEDEN OUT

Eeyan mẹta ni wọn sọ pe ọta ibọn ba.

Ọga ọlọpaa Sweden Anders Thornberg sọ pe awọn onijagidijagan yi ko bikita ẹmi awọn ọlọpaa.

O fikun ọrọ rẹ pe ”a ti ri iwọde ri tẹlẹ amọ eleyi pakasọ”

Igba akọkọ kọ niyi ti iru iṣẹlẹ bayi yoo waye

Awọn iwọde lati tako ipinnu Paludan lati dana sun Quran ti da wahala silẹ tẹlẹ ri ni Sweden.

Ni ọdun 2020 awọn oluwọde dana sun ọkọ ati awọn ẹnu ọna ile itaja ni ikọlu to waye ni Malmo.

Paludan ti wọn sọ sẹwọn f’oṣu kan ni 2020 lori sun ẹlẹyamẹya ni Denmark ti n gbero lati dana sun Quran nita gbangba lawọn orileede Yuroopu mii tofi mọ France ati Belgium.