Wo bí wọ́n ṣe ń lo ìgbẹ́ adìyẹ láti fi pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, gáàsì

Wo bí wọ́n ṣe ń lo ìgbẹ́ adìyẹ láti fi pèsè afẹ́fẹ́ gáàsì ‘biogas’

Adìẹ

Anthony tó jẹ́ àgbẹ̀ bá BBC sọ̀rọ̀ lórí bó ṣe máa ń lo ìgbẹ́ àwọn nǹkan ọ̀sìn láti fi pèsè afẹ́fẹ́ gáàsì “biogas”.

Ó ní ìgbẹ́ adìẹ àti omi àtawọn èròjà mìíràn ni àwọn máa ń tò papọ̀ láti fi pèsè gáàsì yìí.

Ó ṣàlàyé pé ṣsájú àsìkò yìí, ìgbẹ́ màálù ni òun máa ń lò kí òun tó já sí ọgbọ́n lílo ìgbẹ́a dìẹ náà.

Anthony ní ọ̀pọ̀lọps nǹkan ni òun máa ń lo afẹ́fẹ́ gáàsì náà láti fi ṣe bíi fífi ṣe epo sínú ọkọ̀ òun àti láti fi ;mú iná mọ̀nàmọ́ná wọ ilé òun.

Ó fi kun pé òun ni òun ń lò láti máa fi dáná àti láti ṣe gbogbo nǹkan.

Ó ní níwọ̀n ìgbà tí àwọn adìẹ òun bá ṣì ń yàgbẹ́, òun kò nílò ìrònú pé afẹ́fẹ́ gáàsì òun fẹ́ tán.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí